I. Sam 20:24-34
I. Sam 20:24-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Dafidi sì pa ara rẹ̀ mọ li oko; nigbati oṣu titun si de, ọba si joko lati jẹun. Ọba si joko ni ipò rẹ̀ bi igba atijọ lori ijoko ti o gbe ogiri; Jonatani si dide, Abneri si joko ti Saulu, ipò Dafidi si ṣofo. Ṣugbọn Saulu kò sọ nkan nijọ na; nitoriti on rò pe, Nkan ṣe e ni, on ṣe alaimọ́ ni; nitotọ o ṣe alaimọ́ ni. O si ṣe, ni ijọ keji, ti o jẹ ijọ keji oṣu, ipò Dafidi si ṣofo; Saulu si wi fun Jonatani ọmọ rẹ̀ pe, Ẽṣe ti ọmọ Jesse ko fi wá si ibi onjẹ lana ati loni? Jonatani si da Saulu lohùn pe, Dafidi bẹ̀ mi lati lọ si Betlehemu: O si wipe, Jọwọ, jẹ ki emi ki o lọ; nitoripe idile wa li ẹbọ kan iru ni ilu na; ẹgbọn mi si paṣẹ fun mi pe ki emi ki o má ṣaiwà nibẹ; njẹ, bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ rẹ, jọwọ, jẹ ki emi lọ, ki emi ri awọn ẹgbọn mi. Nitorina ni ko ṣe wá si ibi onjẹ ọba. Ibinu Saulu si fà ru si Jonatani, o si wi fun u pe, Iwọ ọmọ ọlọtẹ buburu yi, ṣe emi mọ̀ pe, iwọ ti yàn ọmọ Jesse fun itiju rẹ, ati fun itiju ihoho iya rẹ? Nitoripe ni gbogbo ọjọ ti ọmọ Jesse wà lãye li orilẹ, iwọ ati ijọba rẹ kì yio duro. Njẹ nisisiyi, ranṣẹ ki o si mu u fun mi wá, nitoripe yio kú dandan. Jonatani si da Saulu baba rẹ̀ lohùn, o si wi fun u pe, Nitori kini on o ṣe kú? kili ohun ti o ṣe? Saulu si jù ẹṣín si i lati fi pa a; Jonatani si wa mọ̀ pe baba on ti pinnu rẹ̀ lati pa Dafidi. Bẹ̃ni Jonatani sì fi ibinu dide kuro ni ibi onjẹ, kò si jẹn ní ijọ keji oṣu na: inu rẹ̀ si bajẹ gidigidi fun Dafidi, nitoripe baba rẹ̀ doju tì i.
I. Sam 20:24-34 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi farapamọ́ ninu pápá, ní ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, Saulu ọba jókòó láti jẹun. Ọba jókòó níbi tí ó máa ń jókòó sí ní ẹ̀gbẹ́ ògiri, Jonatani jókòó ní iwájú rẹ̀. Abineri sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Saulu. Ṣugbọn ààyè Dafidi ṣófo. Sibẹ Saulu kò sọ nǹkankan nítorí pé ó rò pé bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi, tí ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ ni. Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?” Jonatani dáhùn pé, “Ó gbààyè lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.” Inú bí Saulu gidigidi sí Jonatani, ó ní, “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ati aláìgbọràn obinrin yìí, mo mọ̀ wí pé ò ń gbè lẹ́yìn Dafidi, o sì ń ta àbùkù ara rẹ ati ìhòòhò ìyá rẹ. Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.” Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?” Saulu bá ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn, ó fẹ́ pa á. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ dájú pé, baba òun pinnu láti pa Dafidi. Jonatani sì fi ibinu dìde kúrò ní ìdí tabili oúnjẹ, kò sì jẹun ní ọjọ́ náà, tíí ṣe ọjọ́ keji oṣù. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.
I. Sam 20:24-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sápamọ́ sínú pápá. Nígbà tí àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun. Ọba sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń jókòó lórí ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jonatani, Abneri sì jókòó ti Saulu, ṣùgbọ́n ààyè Dafidi sì ṣófo. Saulu kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lóòtítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.” Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dafidi sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu wí fún ọmọ rẹ̀ Jonatani pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jese kò fi wá sí ibi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?” Jonatani sì dáhùn pé, “Dafidi bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyìí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.” Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ? Níwọ́n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láààyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹsẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsin yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọdọ̀ kú!” Jonatani béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?” Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni. Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í.