I. Sam 20:1-23
I. Sam 20:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si sa kuro ni Naoti ti Rama, o si wá, o si wi li oju Jonatani pe, Kili emi ṣe? kini ìwa buburu mi, ati kili ẹ̀ṣẹ mi li oju baba rẹ, ti o fi nwá ọ̀na ati pa mi. On si wi fun u pe, Ki a má ri i, iwọ kì yio kú: wõ, baba mi ki yio ṣe nkan nla tabi kekere lai sọ ọ li eti mi, njẹ, esi ti ṣe ti baba mi yio fi pa nkan yi mọ fun mi? nkan na kò ri bẹ̃. Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ, wi, emi o si ṣe e fun ọ. Dafidi si wi fun Jonatani pe, Wõ, li ọla li oṣu titun, emi kò si gbọdọ ṣe alai ba ọba joko lati jẹun; ṣugbọn jẹ ki emi ki o lọ, ki emi si fi ara pamọ li oko titi yio fi di aṣalẹ ijọ kẹta. Bi o ba si ṣepe baba rẹ fẹ mi kù, ki o si wi fun u pe, Dafidi bẹ̀ mi lati sure lọ si Betlehemu ilu rẹ̀: nitoripe ẹbọ ọdun kan kò nibẹ fun gbogbo idile na. Bi o ba wipe, O dara, alafia mbẹ fun iranṣẹ rẹ: ṣugbọn bi o ba binu pupọ, njẹ ki iwọ ki o mọ̀ daju pe buburu ni o nrò ninu rẹ̀. Iwọ o si ṣe ore fun iranṣẹ rẹ, nitoripe iwọ ti mu iranṣẹ rẹ wọ inu majẹmu Oluwa pẹlu rẹ; ṣugbọn bi ìwa buburu ba mbẹ li ọwọ mi, iwọ tikararẹ pa mi; ẽṣe ti iwọ o fi mu mi tọ baba rẹ lọ? Jonatani si wipe, Ki eyini ki o jina si ọ: nitoripe bi emi ba mọ̀ daju pe baba mi npete ibi ti yio wá sori rẹ, njẹ emi le iṣe alaisọ ọ fun ọ bi? Nigbana ni Dafidi wi fun Jonatani pe, Tani yio sọ fun mi? tabi yio ti ri bi baba rẹ ba si fi ìjãnu da ọ lohùn. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Wá, jẹ ki a jade lọ si pápá. Awọn mejeji si jade lọ si pápá. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Oluwa Ọlọrun Israeli, nigbati mo ba si lu baba mi li ohùn gbọ́ li ọla tabi li ọtunla, si wõ, bi ire ba wà fun Dafidi, ti emi kò ba si ranṣẹ si ọ, ti emi kò si sọ ọ li eti rẹ. Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi. Ki iṣe kiki igbà ti mo wà lãye ni iwọ o si ṣe ãnu Oluwa fun mi, ki emi ki o má kú. Ṣugbọn ki iwọ ki o máṣe mu ãnu rẹ kuro ni ile mi lailai: ki isi ṣe igbati Oluwa ke olukuluku ọtá Dafidi kuro lori ilẹ. Bẹ̃ ni Jonatani bá ile Dafidi da majẹmu wipe, Oluwa yio si bere rẹ̀ lọwọ awọn ọta Dafidi. Jonatani si tun mu ki Dafidi ki o bura nitoriti o sa fẹ ẹ: o si fẹ ẹ bi o ti fẹ ẹmi ara rẹ̀. Nigbana ni Jonatani wi fun Dafidi pe, ọla li oṣu titun: a o si fẹ ọ kù, nitoriti ipò rẹ yio ṣofo. Bi iwọ ba si duro ni ijọ mẹta, nigbana ni iwọ o si yara sọkalẹ, iwọ o si wá si ibiti iwọ gbe ti fi ara rẹ pamọ si nigbati iṣẹ na wà lọwọ, iwọ o si joko ni ibi okuta Eseli. Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan. Si wõ, emi o ran ọmọde-kọnrin kan pe, Lọ, ki o si wá ọfa wọnni. Bi emi ba tẹnu mọ ọ fun ọmọkunrin na, pe, Wõ, ọfa wọnni wà lẹhin rẹ, ṣà wọn wá; nigbana ni iwọ o ma bọ̀; nitoriti alafia mbẹ fun ọ, kò si ewu; bi Oluwa ti wà. Ṣugbọn bi emi ba wi bayi fun ọmọde-kọnrin na pe, Wõ ọfa na mbẹ niwaju rẹ; njẹ ma ba tirẹ lọ; Oluwa li o rán ọ lọ. Niti ọ̀rọ ti emi ati iwọ si ti jumọ sọ, wõ, ki Oluwa ki o wà larin iwọ ati emi titi lailai.
I. Sam 20:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi sá kúrò ní Naioti, ní Rama, lọ sọ́dọ̀ Jonatani, ó sì bi í pé, “Kí ni mo ṣe? Ìwà burúkú wo ni mo hù? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ baba rẹ tí ó fi ń wọ́nà láti pa mí?” Jonatani dá a lóhùn pé, “Kí á má rí i, o kò ní kú. Kò sí nǹkankan ti baba mi ń ṣe, bóyá ńlá tabi kékeré, tí kì í sọ fún mi; kò sì tíì sọ èyí fún mi, nítorí náà ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀.” Dafidi dáhùn pé, “Baba rẹ mọ̀ wí pé bí òun bá sọ fún ọ, inú rẹ kò ní dùn, nítorí pé o fẹ́ràn mi. Nítòótọ́ bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, tí ẹ̀mí rẹ náà sì ń bẹ láàyè, ìṣísẹ̀ kan ló wà láàrin èmi ati ikú.” Jonatani bá dáhùn pé, “N óo ṣe ohunkohun tí o bá fẹ́.” Dafidi sọ fún un pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, n kò sì gbọdọ̀ má bá ọba jókòó jẹun. Ṣugbọn jẹ́ kí n lọ farapamọ́ sinu pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta. Bí baba rẹ bá bèèrè mi, sọ fún un pé mo ti gbààyè lọ́wọ́ rẹ láti lọ sí ìlú mi, ní Bẹtilẹhẹmu, nítorí pé àkókò yìí jẹ́ àkókò fún àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ìdílé wa. Bí ó bá sọ pé kò burú, a jẹ́ wí pé alaafia ni fún iranṣẹ rẹ, ṣugbọn bí ó bá bínú gidigidi, èyí yóo fihàn ọ́ wí pé, ó ní ìpinnu burúkú sí mi. Nítorí náà ṣe èmi iranṣẹ rẹ ní oore kan, nítorí o ti mú mi dá majẹmu mímọ́ pẹlu rẹ. Ṣugbọn bí o bá rí ohun tí ó burú ninu ìwà mi, ìwọ gan-an ni kí o pa mí; má wulẹ̀ fà mí lé baba rẹ lọ́wọ́ láti pa.” Jonatani bá dáhùn wí pé, “Má ṣe ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ṣé mo lè mọ̀ dájú pé baba mi fẹ́ pa ọ́, kí n má sọ fún ọ?” Dafidi bá bèèrè pé, “Báwo ni n óo ṣe mọ̀ bí baba rẹ bá bínú?” Jonatani dáhùn pé, “Máa bọ̀, jẹ́ kí á lọ sinu pápá.” Àwọn mejeeji sì lọ. Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣe ẹlẹ́rìí láàrin èmi pẹlu rẹ. Ní àkókò yìí lọ́la tabi ní ọ̀tunla n óo wádìí nípa rẹ̀ lọ́wọ́ baba mi. Bí inú rẹ̀ bá yọ́ sí ọ n óo ranṣẹ sí ọ. Ṣugbọn bí ó bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ níbi, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí OLUWA pa mí bí n kò bá sọ fún ọ, kí n sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sá àsálà. Kí OLUWA wà pẹlu rẹ bí ó ti ṣe wà pẹlu baba mi. Bí mo bá sì wà láàyè kí o fi ìfẹ́ òtítọ́ OLUWA hàn sí mi kí n má baà kú. Ṣugbọn bí mo bá kú, má jẹ́ kí àánú rẹ kúrò ninu ilé mi títí lae. Nígbà tí OLUWA bá ti ké gbogbo àwọn ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, má jẹ́ kí orúkọ Jonatani di ìkékúrò ní ilé Dafidi. Kí OLUWA gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá Dafidi.” Jonatani tún mú kí Dafidi ṣe ìbúra lẹ́ẹ̀kan sí i, pẹlu ìfẹ́ tí ó ní sí i. Nítorí pé, Jonatani fẹ́ràn rẹ̀ bí ó ti fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, àwọn eniyan yóo sì mọ̀ bí o kò bá wá síbi oúnjẹ nítorí ààyè rẹ yóo ṣófo. Bí wọn kò bá rí ọ ní ọjọ́ keji, wọn yóo mọ̀ dájú pé o kò sí láàrin wọn. Nítorí náà, lọ sí ibi tí o farapamọ́ sí ní ìjelòó, kí o sì farapamọ́ sẹ́yìn àwọn òkúta ọ̀hún nnì. N óo sì ta ọfà mẹta sí ìhà ibẹ̀ bí ẹni pé mo ta wọ́n sí àmì kan. N óo rán ọmọkunrin kan láti wá àwọn ọfà náà. Bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wò ó àwọn ọfà náà wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,’ kí o jáde wá, nítorí bí OLUWA tí ń bẹ, kò sí ewu kankan fún ọ. Ṣugbọn bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wo àwọn ọfà náà níwájú rẹ,’ máa bá tìrẹ lọ nítorí OLUWA ni ó fẹ́ kí o lọ. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi pẹlu rẹ jọ sọ, ranti pé OLUWA wà láàrin wa laelae.”
I. Sam 20:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Dafidi sá kúrò ní Naioti ti Rama ó sì lọ sọ́dọ̀ Jonatani ó sì béèrè pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi?” Jonatani dáhùn pé, “Kí a má rí i! Ìwọ kò ní kú! Wò ó baba mi kì í ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí tí ó kéré, láìfi lọ̀ mí. Èéṣe tí yóò fi fi èyí pamọ́ fún mi? Kò rí bẹ́ẹ̀.” Ṣùgbọ́n Dafidi tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojúrere ní ojú rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jonatani kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Síbẹ̀ nítòótọ́ bí OLúWA ti wà láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láààyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrín ìyè àti ikú.” Jonatani wí fún Dafidi pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.” Dafidi sì wí fún Jonatani pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ̀ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta. Bí ó bá sì ṣe pé baba rẹ bá fẹ́ mi kù, kí o sì wí fún un pé, ‘Dafidi fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí Bẹtilẹhẹmu ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’ Tí o bá wí pé, ‘Àlàáfíà ni,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi. Ṣùgbọ́n ní tìrẹ ìwọ, fi ojúrere wo ìránṣẹ́ rẹ; nítorí tí ìwọ ti bá a dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú OLúWA. Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́?” Jonatani wí pé, “Kí a má rí i! Ti mo bá ti gbọ́ tí baba mi ti pinnu láti pa ọ́ lára, ṣé èmi kò ní sọ fún ọ?” Nígbà náà ni Dafidi sì wí fún Jonatani pé, “Ta ni yóò sọ fún mi tí baba rẹ̀ bá dá ọ lóhùn ní ohùn líle?” Jonatani wí fún Dafidi pé, “Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá.” Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ. Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé: “Mo fi OLúWA Ọlọ́run àwọn Israẹli búra pé, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla! Bí ó bá sì ní inú dídùn sí ọ, èmi yóò ránṣẹ́ sí ọ, èmi yóò sì jẹ́ kí o mọ̀? Ṣùgbọ́n tí baba mi bá fẹ́ pa ọ́ lára, kí OLúWA kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí Jonatani; tí èmi kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí OLúWA kí ó wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi. Ṣùgbọ́n fi àìkùnà inú rere hàn mí bí inú rere OLúWA, níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè kí wọ́n má ba à pa mí, Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí OLúWA tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀.” Nígbà náà ni Jonatani bá ilé Dafidi dá májẹ̀mú wí pé, “OLúWA yóò pe àwọn àti Dafidi láti ṣírò” Jonatani mú kí Dafidi tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀. Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a yóò fẹ́ ọ kù, nítorí ààyè rẹ yóò ṣófo. Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí ibi tí o sápamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Eselu. Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí ààmì ibìkan. Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún un wí pé, ‘wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ; kó wọn wá síbí,’ kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewu. Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, ‘Wò ó, àwọn ọfà náà ń bẹ níwájú rẹ,’ ǹjẹ́ máa bá tìrẹ lọ, nítorí OLúWA ni ó rán ọ lọ. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí OLúWA jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti èmi títí láéláé.”