I. Sam 2:6-8
I. Sam 2:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa pa, o si sọ di ayè: o mu sọkalẹ lọ si ibojì, o si gbe soke. Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbe soke. O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn.
I. Sam 2:6-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ni ó lè pa eniyan tán, kí ó sì tún jí i dìde; òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú, tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀. OLUWA ni ó lè sọni di aláìní, òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀. Òun ni ó ń gbéni ga, òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀. OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.
I. Sam 2:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“OLúWA pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. OLúWA sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo