I. Sam 2:1-26

I. Sam 2:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

HANNA si gbadura pe, Ọkàn mi yọ̀ si Oluwa, iwo mi li a si gbe soke si Oluwa: ẹnu mi si gboro lori awọn ọta mi; nitoriti emi yọ̀ ni igbala rẹ. Kò si ẹniti o mọ́ bi Oluwa: kò si ẹlomiran boyẹ̀ ni iwọ; bẹ̃ni kò si apata bi Ọlọrun wa. Máṣe halẹ; má jẹ ki igberaga ki o ti ẹnu nyin jade: nitoripe Ọlọrun olùmọ̀ ni Oluwa, lati ọdọ rẹ̀ wá li ati iwọ̀n ìwa. Ọrun awọn alagbara ti ṣẹ, awọn ti o ṣe alailera li a fi agbara dì li amure. Awọn ti o yo fun onjẹ ti fi ara wọn ṣe alagbaṣe: awọn ti ebi npa kò si ṣe alaini: tobẹ̃ ti àgan fi bi meje: ẹniti o bimọ pipọ si di alailagbara. Oluwa pa, o si sọ di ayè: o mu sọkalẹ lọ si ibojì, o si gbe soke. Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbe soke. O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn. Yio pa ẹṣẹ awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ, awọn enia buburu ni yio dakẹ li okunkun; nipa agbara kò si ọkunrin ti yio bori. Ao fọ́ awọn ọta Oluwa tutu; lati ọrun wá ni yio san ãrá si wọn: Oluwa yio ṣe idajọ opin aiye; yio fi agbara fun ọba rẹ̀, yio si gbe iwo ẹni-amì-ororo rẹ̀ soke. Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa. Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ Oluwa. Iṣe awọn alufa pẹlu awọn enia ni, nigbati ẹnikan ba ṣe irubọ, iranṣẹ alufa a de, nigbati ẹran na nho lori iná, ti on ti ọpa-ẹran oniga mẹta li ọwọ́ rẹ̀. On a si fi gun inu apẹ, tabi kẹtili tabi òdu, tabi ikokò, gbogbo eyi ti ọpa-ẹran oniga na ba mu wá oke, alufa a mu u fun ara rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn nṣe si gbogbo Israeli ti o wá si ibẹ̀ ni Ṣilo. Pẹlu ki nwọn ki o to sun ọra na, iranṣẹ alufa a de, a si wi fun ọkunrin ti on ṣe irubọ pe, Fi ẹran fun mi lati sun fun alufa; nitoriti kì yio gba ẹran sisè lọwọ rẹ, bikoṣe tutù. Ọkunrin na si wi fun u pe, Jẹ ki wọn sun ọra na nisisiyi, ki o si mu iyekiye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana li o da a lohun pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ki iwọ ki o fi i fun mi nisisiyi: bikoṣe bẹ̃, emi o fi agbara gbà a. Ẹṣẹ awọn ọdọmọkunrin na si tobi gidigidi niwaju Oluwa: nitoriti enia korira ẹbọ Oluwa. Ṣugbọn Samueli nṣe iranṣẹ niwaju Oluwa, o ṣe ọmọde, ti a wọ̀ ni efodi ọgbọ. Pẹlupẹlu iya rẹ̀ da aṣọ ileke penpe fun u, a ma mu fun u wá lọdọdun, nigbati o ba bá ọkọ rẹ̀ goke wá lati ṣe irubọ ọdun. Eli sure fun Elkana ati aya rẹ̀ pe ki Oluwa ki o ti ara obinrin yi fun ọ ni iru-ọmọ nipa ibere na ti o bere lọdọ Oluwa. Nwọn si lọ si ile wọn. Oluwa si boju wo Hanna, o si loyun, o bi ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin meji. Samueli ọmọ na si ndagbà niwaju Oluwa. Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ. O si wi fun wọn pe, Etiri ti emi fi ngbọ́ iru nkan bẹ̃ si nyin? nitoriti emi ngbọ́ iṣe buburu nyin lati ọdọ gbogbo enia yi wá. Bẹ̃kọ, ẹnyin ọmọ mi, nitori ki iṣe ihinrere li emi gbọ́: ẹnyin mu enia Ọlọrun dẹṣẹ̀. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn. Ọmọ na Samueli ndagba, o si ri ojurere lọdọ Oluwa, ati enia pẹlu.

I. Sam 2:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Hana bá gbadura báyìí pé: “Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA, Ó sọ mí di alágbára; mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín, nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là. “Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA, kò sí ẹlòmíràn, àfi òun nìkan ṣoṣo. Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa. Má sọ̀rọ̀ pẹlu ìgbéraga mọ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu rẹ jáde, nítorí Ọlọrun tí ó mọ ohun gbogbo ni OLUWA, gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ni ó sì máa ń gbéyẹ̀wò. Ọrun àwọn alágbára dá, ṣugbọn àwọn aláìlágbára di alágbára. Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó rí ti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ, ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó. Àgàn ti di ọlọ́mọ meje, ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní. OLUWA ni ó lè pa eniyan tán, kí ó sì tún jí i dìde; òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú, tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀. OLUWA ni ó lè sọni di aláìní, òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀. Òun ni ó ń gbéni ga, òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀. OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn. “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́, ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn; nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun. Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun; OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá. OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé, yóo fún ọba rẹ̀ lágbára, yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.” Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli. Aláìníláárí ẹ̀dá ni àwọn ọmọ Eli mejeeji. Wọn kò bọ̀wọ̀ fún OLUWA rárá. Ó jẹ́ àṣà àwọn alufaa pé nígbà tí ẹnìkan bá wá rúbọ, iranṣẹ alufaa yóo wá, ti òun ti ọ̀pá irin oníga mẹta tí wọ́n fi ń yọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń se ẹran náà lọ́wọ́ lórí iná, yóo ti ọ̀pá irin náà bọ inú ìkòkò ẹran, gbogbo ẹran tí ó bá yọ jáde á jẹ́ ti alufaa. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá wá rúbọ ní Ṣilo. Ati pé, kí wọ́n tilẹ̀ tó rẹ́ ọ̀rá tí wọ́n máa ń sun kúrò lára ẹran, iranṣẹ alufaa á wá, a sì wí fún ẹni tí ń rú ẹbọ pé kí ó fún òun ninu ẹran tí alufaa yóo sun jẹ, nítorí pé alufaa kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ olúwarẹ̀, àfi ẹran tútù. Bí ẹni tí ń rú ẹbọ náà bá dá a lóhùn pé “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ sun ọ̀rá ẹran náà, lẹ́yìn náà kí o wá mú ohun tí ó bá wù ọ́.” Iranṣẹ alufaa náà á wí pé, “Rárá! Nisinsinyii ni kí o fún mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo mú un tipátipá.” Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ọmọ Eli ń dá yìí burú pupọ lójú OLUWA, nítorí pé wọn kò náání ẹbọ OLUWA. Ní gbogbo àkókò yìí, Samuẹli ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, ó sì jẹ́ ọmọde nígbà náà, a máa wọ ẹ̀wù efodu funfun. Ní ọdọọdún ni ìyá rẹ̀ máa ń dá ẹ̀wù kékeré, a sì mú un lọ́wọ́ lọ fún un, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ lọ, láti lọ rúbọ. Eli a máa súre fún Elikana ati Hana aya rẹ̀ pé, “OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí ọmọ mìíràn fún ọ, dípò èyí tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.” Lẹ́yìn náà, wọn yóo pada lọ sí ilé wọn. OLUWA bukun Hana: ọmọkunrin mẹta, ati ọmọbinrin meji ni ó tún bí lẹ́yìn Samuẹli. Samuẹli sì ń dàgbà níbi tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA. Eli ti di arúgbó gan-an ní àkókò yìí. Ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli, ati bí wọ́n ti ṣe ń bá àwọn obinrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ lòpọ̀. A máa bi wọ́n léèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe báyìí? Gbogbo ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù sí àwọn eniyan ni mò ń gbọ́. Ẹ̀yin ọmọ mi, ọ̀rọ̀ burúkú ni àwọn eniyan OLUWA ń sọ káàkiri nípa yín. Bí ẹnìkan bá ṣẹ eniyan, Ọlọrun lè parí ìjà láàrin wọn; ṣugbọn bí eniyan bá ṣẹ OLUWA, ta ni yóo bá a bẹ̀bẹ̀?” Ṣugbọn àwọn ọmọ Eli kò gbọ́ ti baba wọn, nítorí pé OLUWA ti pinnu láti pa wọ́n. Samuẹli ń dàgbà sí i, ó sì ń bá ojurere OLUWA ati ti eniyan pàdé.

I. Sam 2:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLúWA; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLúWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLúWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa. “Má ṣe halẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni OLúWA, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà. “Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè. Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní. Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje. Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára. “OLúWA pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. OLúWA sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo: “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti OLúWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn. “Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí. A ó fọ́ àwọn ọ̀tá OLúWA túútúú; láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn; OLúWA yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé. “Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀, yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.” Elkana sì lọ sí Rama sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún OLúWA níwájú Eli àlùfáà. Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ OLúWA. Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo. Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.” Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́,” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.” Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú OLúWA: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ OLúWA. Ṣùgbọ́n Samuẹli ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú OLúWA, ọmọdé, ti a wọ̀ ní efodu ọ̀gbọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mú wá fún un lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún. Eli súre fún Elkana àti aya rẹ̀ pé, “Kí OLúWA fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún OLúWA.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn. OLúWA si bojú wo Hana, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Samuẹli ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú OLúWA. Eli sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Israẹli; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹ̀yin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí OLúWA, ta ni yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí OLúWA ń fẹ́ pa wọ́n. Ọmọ náà Samuẹli ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ OLúWA, àti ènìyàn pẹ̀lú.

I. Sam 2:1-26

I. Sam 2:1-26 YBCVI. Sam 2:1-26 YBCVI. Sam 2:1-26 YBCVI. Sam 2:1-26 YBCV