I. Sam 19:1-4
I. Sam 19:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
SAULU si sọ fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o pa Dafidi. Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ. Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ. Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ.
I. Sam 19:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Saulu sọ fún ọmọ rẹ̀ Jonatani ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣugbọn Jonatani fẹ́ràn Dafidi lọpọlọpọ. Ó sì sọ fún Dafidi pé, “Baba mi fẹ́ pa ọ́, nítorí náà fi ara pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan lọ́la, kí o má ṣe wá sí gbangba. N óo dúró pẹlu baba mi ní orí pápá lọ́la níbi tí o bá farapamọ́ sí, n óo sì bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ, ohunkohun tí mo bá sì gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, n óo sọ fún ọ.” Jonatani sọ̀rọ̀ Dafidi ní rere níwájú Saulu, ó wí pé, “Kabiyesi, má ṣe nǹkankan burúkú sí iranṣẹ rẹ, Dafidi, nítorí kò ṣe ibi kan sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ń ṣe ni ó ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ọ.
I. Sam 19:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀ Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sápamọ́ sí ibẹ̀. Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.” Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.