I. Sam 18:6-9
I. Sam 18:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru. Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀. Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba. Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ.
I. Sam 18:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé, “Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀, ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.” Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.” Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi.
I. Sam 18:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti pa Filistini, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Israẹli wá láti pàdé ọba Saulu pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tambori àti ohun èlò orin olókùn. Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé: “Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀ Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárún ní tirẹ̀.” Saulu sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dafidi pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?” Láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlara wo Dafidi.