I. Sam 17:28-30
I. Sam 17:28-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eliabu ẹgbọn rẹ̀ si gbọ́ nigbati on ba awọn ọkunrin na sọ̀rọ; Eliabu si binu si Dafidi, o si wipe, Ẽ ti ṣe ti iwọ fi sọkalẹ wá ihinyi, tani iwọ ha fi agutan diẹ nì le lọwọ́ li aginju? emi mọ̀ igberaga rẹ, ati buburu ọkàn rẹ; nitori lati ri ogun ni iwọ ṣe sọkalẹ wá. Dafidi si dahùn wipe, Kini mo ṣe nisisiyi? ko ha ni idi bi? On si yipada kuro lọdọ rẹ̀ si ẹlomiran, o si sọ bakanna: awọn enia na si fi esì fun u gegẹ bi ọ̀rọ iṣaju.
I. Sam 17:28-30 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.” Dafidi sì dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe nisinsinyii? Ṣebí ọ̀rọ̀ lásán ni mò ń sọ.” Dafidi yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, ó tún bèèrè ìbéèrè kan náà. Àwọn ọkunrin náà sì fún un ní èsì bíi ti iṣaaju.
I. Sam 17:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Eliabu ẹ̀gbọ́n Dafidi gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tókù ṣọ́ ní aginjù? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.” Dafidi wí pé, “Kí ni mo ṣe nísinsin yìí? Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí?” Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kan náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú.