I. Sam 16:11-13
I. Sam 16:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli si bi Jesse lere pe, gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi? On si dahun wipe, abikẹhin wọn li o kù, sa wõ, o nṣọ agutan. Samueli si wi fun Jesse pe, Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa kì yio joko titi on o fi dé ihinyi. O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi. Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.

I. Sam 16:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?” Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.” Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.” Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama.
I. Sam 16:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?” Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.” Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.” Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi. Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí mímọ́ OLúWA wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama.