I. Sam 15:1-16

I. Sam 15:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

SAMUELI si wi fun Saulu pe, Oluwa rán mi lati fi ami ororo yàn ọ li ọba, lori enia rẹ̀, lori Israeli, nitorina nisisiyi iwọ fetisi ohùn ọ̀rọ Oluwa. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ranti eyi ti Amaleki ti ṣe si Israeli, bi o ti lumọ dè e li ọ̀na, nigbati on goke ti Egipti jade wá. Lọ nisisiyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan wọn li aparun, má si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, malu ati agutan, ibakasiẹ ati kẹtẹkẹtẹ. Saulu si ko awọn enia na jọ pọ̀ o si ka iye wọn ni Telaimu, nwọn si jẹ ogun ọkẹ awọn ọkunrin ogun ẹlẹsẹ, pẹlu ẹgbarun awọn ọkunrin Juda. Saulu si wá si ilu-nla kan ti awọn ara Amaleki, o si ba dè wọn li afonifoji kan. Saulu si wi fun awọn Keniti pe, Ẹ lọ, yẹra kuro larin awọn ara Amaleki, ki emi ki o má ba run nyin pẹlu wọn: nitoripe ẹnyin ṣe ore fun gbogbo awọn ọmọ Israeli nigbati nwọn goke ti Egipti wá. Awọn Keniti yẹra kuro larin Amaleki. Saulu si kọlu Amaleki lati Hafila titi iwọ o fi de Ṣuri, ti o wà li apa keji Egipti. O si mu Agagi Ọba Amaleki lãye, o si fi oju ida run gbogbo awọn enia na. Ṣugbọn Saulu ati awọn enia na da Agagi si, ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu malu, ati ohun eyi ti o dara tobẹ̃ ninu wọn, ati ọdọ-agutan abọpa, ati gbogbo nkan ti o dara; nwọn kò si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nkan ti kò dara ti kò si nilari ni nwọn parun patapata. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe, Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na. Nigbati Samueli si dide ni kutukutu owurọ̀ lati pade Saulu, nwọn si sọ fun Samueli pe, Saulu ti wá si Karmeli, sa wõ, on kọ ibi kan fun ara rẹ̀ o si ti lọ, o si kọja siwaju, o si sọkalẹ lọ si Gilgali. Samueli si tọ Saulu wá: Saulu si wi fun u pe, Alabukún ni ọ lati ọdọ Oluwa wá: emi ti ṣe eyi ti Oluwa ran mi. Samueli si wipe, njẹ ewo ni igbe agutan ti emi ngbọ́ li eti mi, ati igbe malu ti emi ngbọ́? Saulu si wi fun u pe, eyi ti nwọn mu ti Amaleki wá ni, ti awọn enia dasi ninu awọn agutan ton ti malu ti o dara julọ lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ; a si pa eyi ti o kù run. Samueli si wi fun Saulu pe, Duro, emi o si sọ eyi ti Oluwa wi fun mi li alẹ yi. On si wi fun u pe, Ma wi.

I. Sam 15:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Samuẹli sọ fún Saulu pé, “OLUWA rán mi láti fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, eniyan rẹ̀. Nisinsinyii gbọ́ ohun tí OLUWA wí. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo jẹ àwọn ará Amaleki níyà nítorí pé wọ́n gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti. Lọ gbógun ti àwọn ará Amaleki, kí o sì run gbogbo nǹkan tí wọ́n ní patapata. O kò gbọdọ̀ dá nǹkankan sí, pa gbogbo wọn, atọkunrin, atobinrin; àtàwọn ọmọ kéékèèké; àtàwọn ọmọ ọmú; ati mààlúù, ataguntan, ati ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, gbogbo wọn pátá ni kí o pa.’ ” Saulu bá kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó ka iye wọn ní Telaimu. Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000). Òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá lọ sí ìlú Amaleki, wọ́n ba ní ibùba, ní àfonífojì. Saulu ranṣẹ ìkìlọ̀ kan sí àwọn ará Keni pé, “Ẹ jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki, kí n má baà pa yín run, nítorí pé ẹ̀yin ṣàánú àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.” Àwọn ará Keni bá jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki. Saulu ṣẹgun àwọn ará Amaleki láti Hafila títí dé Ṣuri ní ìhà ìlà oòrùn Ijipti. Ó mú Agagi, ọba àwọn ará Amaleki láàyè, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. Ṣugbọn Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ dá Agagi sí, wọn kò sì pa àwọn tí wọ́n dára jùlọ ninu àwọn aguntan, mààlúù, ati ọ̀dọ́ mààlúù ati ọ̀dọ́ aguntan wọn, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó dára. Wọn kò pa wọ́n run, ṣugbọn wọ́n pa àwọn ohun tí kò níláárí run. OLUWA sọ fún Samuẹli pé, “Ó dùn mí pé mo fi Saulu jọba. Ó ti yipada kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa òfin mi mọ́.” Inú bí Samuẹli, ó sì gbadura sí OLUWA ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ó jáde, ó lọ rí Saulu. Ó gbọ́ pé Saulu ti lọ sí Kamẹli, níbi tí ó ti gbé ọ̀wọ̀n kan kalẹ̀, ní ìrántí ara rẹ̀, ati pé ó ti gba ibẹ̀ lọ sí Giligali. Samuẹli bá lọ sọ́dọ̀ Saulu. Saulu sọ fún un pé, “Kí OLUWA kí ó bukun ọ, Samuẹli, mo ti pa òfin OLUWA mọ́.” Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ni igbe àwọn aguntan ati ti àwọn mààlúù tí mò ń gbọ́ yìí?” Saulu dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan mi ni wọ́n kó wọn lọ́dọ̀ àwọn ará Amaleki. Wọ́n ṣa àwọn aguntan ati àwọn mààlúù tí wọ́n dára jùlọ pamọ́ láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ. A sì ti pa gbogbo àwọn yòókù run patapata.” Samuẹli bá sọ fún un pé, “Dákẹ́! Jẹ́ kí n sọ ohun tí OLUWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.” Saulu dáhùn pé, “Mò ń gbọ́.”

I. Sam 15:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Samuẹli wí fún Saulu pé, “Èmi ni OLúWA rán láti fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli; fetísílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí OLúWA rán mi sí ọ́. Èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi yóò jẹ àwọn Amaleki ní yà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ejibiti. Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọlu Amaleki, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tiwọn ní à parun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Saulu kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Talaemu, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (200,000) àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárùn-ún àwọn ọkùnrin Juda (10,000). Saulu sì lọ sí ìlú Amaleki ó sì gọ dè wọ́n ní Àfonífojì kan. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ará Keni pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Amaleki kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè ti Ejibiti wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kenaiti lọ kúrò láàrín àwọn Amaleki. Nígbà náà ni Saulu kọlu àwọn Amaleki láti Hafila dé Ṣuri, tí ó fi dé ìlà-oòrùn Ejibiti. Ó sì mú Agagi ọba Amaleki láààyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlù gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n Saulu àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ dá Agagi sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátápátá ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì níláárí ni wọ́n parun pátápátá. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Samuẹli wá pé: “Èmi káàánú gidigidi pé mo fi Saulu jẹ ọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Samuẹli sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì ké pe OLúWA ní gbogbo òru náà. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Samuẹli sì dìde láti lọ pàdé Saulu, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Saulu ti wá sí Karmeli. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gilgali.” Nígbà tí Samuẹli sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Saulu sì wí fún un pé, “OLúWA bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí OLúWA pàṣẹ.” Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?” Saulu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ní o mú wọn láti Amaleki wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rú ẹbọ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tókù run pátápátá.” Samuẹli sí wí fún Saulu pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí OLúWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.” Saulu sì wí pé, “Sọ fún mi.”