I. Sam 14:6-15
I. Sam 14:6-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là. Ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ na wi fun u pe, Ṣe gbogbo eyi ti o mbẹ li ọkàn rẹ: ṣe bi o ti tọ́ li ọkàn rẹ; wõ, emi wà pẹlu rẹ gẹgẹ bi ti ọkàn rẹ. Jonatani si wi pe, Kiye si i, awa o rekọja sọdọ awọn ọkunrin wọnyi, a o si fi ara wa hàn fun wọn. Bi nwọn ba wi fun wa pe, Ẹ duro titi awa o fi tọ̀ nyin wá; awa o si duro, awa kì yio si goke tọ̀ wọn lọ. Ṣugbọn bi nwọn ba wi pe, Goke tọ̀ wa wá; a o si goke lọ: nitori pe Oluwa ti fi wọn le wa lọwọ́; eyi ni o si jẹ àmi fun wa. Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si. Awọn ọkunrin ile olodi na si da Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, Goke tọ̀ wa wá, awa o si fi nkan hàn nyin; Jonatani si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Ma tọ̀ mi lẹhìn; nitoripe Oluwa ti fi wọn le awọn enia Israeli lọwọ. Jonatani rakò goke, ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lẹhin rẹ̀; awọn Filistini si subu niwaju Jonatani; ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ npa lẹhin rẹ̀. Pipa ikini, eyi ti Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ ṣe, o jasi iwọn ogún ọkunrin ninu abọ iṣẹko kan ti malu meji iba tú. Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla.
I. Sam 14:6-15 Yoruba Bible (YCE)
Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.” Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Ohunkohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́ ni kí o ṣe. Mo wà lẹ́yìn rẹ, bí ọkàn rẹ ti rí ni tèmi náà rí.” Jonatani bá dáhùn pé, “Ó dára, a óo rékọjá sọ́hùn-ún, a óo sì fi ara wa han àwọn ará Filistia. Bí wọ́n bá ní kí á dúró kí àwọn tọ̀ wá wá, a óo dúró níbi tí a bá wà, a kò ní lọ sọ́dọ̀ wọn. Ṣugbọn bí wọ́n bá ní kí á máa bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn, a óo tọ̀ wọ́n lọ. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún wa, pé OLUWA ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Nítorí náà, wọ́n fi ara wọn han àwọn ará Filistia. Bí àwọn ara Filistia ti rí wọn, wọ́n ní, “Ẹ wò ó! Àwọn Heberu ń jáde bọ̀ wá láti inú ihò òkúta tí wọ́n farapamọ́ sí.” Wọ́n bá nahùn pe Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀; wọ́n ní, “Ẹ máa gòkè tọ̀ wá bọ̀ níhìn-ín, a óo fi nǹkankan hàn yín.” Jonatani bá wí fún ọdọmọkunrin náà pé, “Tẹ̀lé mi, OLUWA ti fún Israẹli ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Jonatani bá rápálá gun òkè náà, ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Jonatani bá bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará Filistia jà, wọ́n sì ń ṣubú níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣubú ni ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ń pa wọ́n. Ní àkókò tí wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, Jonatani ati ọdọmọkunrin yìí pa nǹkan bí ogún eniyan. Ààrin ibi tí wọ́n ti ja ìjà yìí kò ju nǹkan bí ìdajì sarè oko kan lọ. Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn ará Filistia tí wọ́n wà ní ibùdó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, ati gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ ogun Filistini ati àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n ń digun-jalè wárìrì, ilẹ̀ mì tìtì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo wọn.
I. Sam 14:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá OLúWA yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di OLúWA lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.” Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú; Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.” Jonatani sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa. Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún wa pé OLúWA ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.” Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.” Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.” Jonatani sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; OLúWA ti fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́.” Jonatani lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Filistini sì ṣubú níwájú Jonatani ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní ìkọlù èkínní yìí, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbègbè tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sáré ilẹ̀. Nígbà náà ni ìbẹ̀rùbojo bá àwọn ọmọ-ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.