I. Sam 14:24-34
I. Sam 14:24-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ. Gbogbo awọn ara ilẹ na si de igbo kan, oyin sì wà lori ilẹ na. Nigbati awọn enia si wọ inu igbo na, si kiye si i oyin na nkán; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o mu ọwọ́ rẹ̀ re ẹnu rẹ̀: nitoripe awọn enia bẹ̀ru ifibu na. Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nigbati baba rẹ̀ fi ifibu kilọ fun awọn enia na: o si tẹ ori ọpa ti mbẹ lọwọ rẹ̀ bọ afara oyin na, o si fi i si ẹnu rẹ̀, oju rẹ̀ mejeji si walẹ. Nigbana li ọkan ninu awọn enia na dahùn wipe, baba rẹ ti fi ifibu kilọ fun awọn enia na, pe, ifibu li ọkunrin na ti o jẹ onjẹ li oni. Arẹ̀ si mu awọn enia na. Nigbana ni Jonatani wipe, baba mi yọ ilu li ẹnu, sa wo bi oju mi ti walẹ, nitori ti emi tọ diẹ wò ninu oyin yi. A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to? Nwọn pa ninu awọn Filistini li ọjọ na, lati Mikmaṣi de Aijaloni: o si rẹ̀ awọn enia na gidigidi. Awọn enia sare si ikogun na, nwọn si mu agutan, ati malu, ati ọmọ-malu, nwọn si pa wọn sori ilẹ: awọn enia na si jẹ wọn t'ẹjẹ t'ẹjẹ. Nigbana ni nwọn wi fun Saulu pe, kiye si i, awọn enia na dẹ̀ṣẹ si Oluwa, li eyi ti nwọn jẹ ẹjẹ. On si wipe, Ẹnyin ṣẹ̀ kọja: yi okuta nla fun mi wá loni. Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀.
I. Sam 14:24-34 Yoruba Bible (YCE)
Ara àwọn ọmọ ogun Israẹli ti hù ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ sì mú wọn, nítorí pé Saulu ti fi ìbúra pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan títí di àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, títí tí òun yóo fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá òun, olúwarẹ̀ gbé! Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wọn tí ó fi ẹnu kan nǹkankan. Gbogbo wọn dé inú igbó, wọ́n rí oyin nílẹ̀. Nígbà tí wọ́n wọ inú igbó náà, wọ́n rí i tí oyin ń kán sílẹ̀, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè fi ọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra Saulu. Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ ń fi ìbúra pàṣẹ fún àwọn eniyan náà. Nítorí náà, ó na ọ̀pá tí ó mú lọ́wọ́, ó tì í bọ inú afárá oyin kan, ó sì lá a. Lẹsẹkẹsẹ ojú rẹ̀ wálẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn eniyan náà wí fún un pé, “Ebi ń pa gbogbo wa kú lọ, ṣugbọn baba rẹ ti búra pé, ‘Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan lónìí.’ ” Jonatani dáhùn pé, “Ohun tí baba mi ṣe sí àwọn eniyan wọnyi kò dára, wò ó bí ojú mi ti wálẹ̀ nígbà tí mo lá oyin díẹ̀. Báwo ni ìbá ti dára tó lónìí, bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan jẹ lára ìkógun àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí. Àwọn ará Filistia tí wọn ìbá pa ìbá ti pọ̀ ju èyí lọ.” Wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini ní ọjọ́ náà, láti Mikimaṣi títí dé Aijaloni; ó sì rẹ àwọn eniyan náà gidigidi. Nítorí náà, wọ́n sáré sí ìkógun, wọ́n pa àwọn aguntan ati mààlúù ati ọmọ mààlúù, wọ́n sì ń jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀. Wọ́n bá lọ sọ fún Saulu pé, “Àwọn eniyan ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.” Saulu bá wí pé, “Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni ẹ hù yìí. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.” Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.
I. Sam 14:24-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Saulu ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ. Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà. Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ síbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré. Ṣùgbọ́n Jonatani kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.” Jonatani sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdààmú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí. Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀tá wọn lónìí, pípa àwọn Filistini ìbá ti pọ̀ tó?” Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti pa nínú àwọn Filistini láti Mikmasi dé Aijaloni, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà. Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀. Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLúWA nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.” Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí OLúWA, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.