I. Sam 14:1-23

I. Sam 14:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe li ọjọ kan, Jonatani ọmọ Saulu si wi fun ọdọmọkunrin ti o nru ihamọra rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a rekọja lọ si ibudo-ogun awọn Filistini ti o wà niha keji. Ṣugbọn on kò sọ fun baba rẹ̀. Saulu si duro ni iha ipinlẹ Gibea labẹ igi ìbo eyi ti o wà ni Migronu: awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ to iwọn ẹgbẹta ọkunrin. Ahia ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, alufa Oluwa ni Ṣilo, ti nwọ̀ Efodu. Awọn enia na kò si mọ̀ pe Jonatani ti lọ. Larin meji ọ̀na wọnni, eyi ti Jonatani ti nwá lati lọ si ile ọmọ-ogun olodi ti Filistini, okuta mimú kan wà li apa kan, okuta mímú kan si wà li apa keji: orukọ ekini si njẹ Bosesi, orukọ ekeji si njẹ Sene. Ṣonṣo okuta ọkan wà ni ariwa kọju si Mikmaṣi, ti ekeji si wà ni gusù niwaju Gibea. Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là. Ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ na wi fun u pe, Ṣe gbogbo eyi ti o mbẹ li ọkàn rẹ: ṣe bi o ti tọ́ li ọkàn rẹ; wõ, emi wà pẹlu rẹ gẹgẹ bi ti ọkàn rẹ. Jonatani si wi pe, Kiye si i, awa o rekọja sọdọ awọn ọkunrin wọnyi, a o si fi ara wa hàn fun wọn. Bi nwọn ba wi fun wa pe, Ẹ duro titi awa o fi tọ̀ nyin wá; awa o si duro, awa kì yio si goke tọ̀ wọn lọ. Ṣugbọn bi nwọn ba wi pe, Goke tọ̀ wa wá; a o si goke lọ: nitori pe Oluwa ti fi wọn le wa lọwọ́; eyi ni o si jẹ àmi fun wa. Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si. Awọn ọkunrin ile olodi na si da Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, Goke tọ̀ wa wá, awa o si fi nkan hàn nyin; Jonatani si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Ma tọ̀ mi lẹhìn; nitoripe Oluwa ti fi wọn le awọn enia Israeli lọwọ. Jonatani rakò goke, ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lẹhin rẹ̀; awọn Filistini si subu niwaju Jonatani; ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ npa lẹhin rẹ̀. Pipa ikini, eyi ti Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ ṣe, o jasi iwọn ogún ọkunrin ninu abọ iṣẹko kan ti malu meji iba tú. Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla. Awọn ọkunrin ti nṣọ́na fun Saulu ni Gibea ti Benjamini wò; nwọn si ri ọpọlọpọ awọn enia na tuka, nwọn si npa ara wọn bi nwọn ti nlọ. Saulu si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ kà awọn enia na ki ẹ si mọ̀ ẹniti o jade kuro ninu wa. Nwọn si kà, si kiye si i, Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ kò si si. Saulu si wi fun Ahia pe, Gbe apoti Ọlọrun na wá nihinyi. Nitoripe apoti Ọlọrun wà lọdọ awọn ọmọ Israeli li akokò na. O si ṣe, bi Saulu ti mba alufa na sọ̀rọ, ariwo ti o wà ni budo awọn Filistini si npọ̀ si i: Saulu si wi fun alufa na pe, dawọ́ duro. Saulu ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀ ko ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá si oju ija: kiye si i, ida olukuluku si wà li ara ọmọnikeji rẹ̀, rudurudu na si pọ̀ gidigidi. Pẹlupẹlu awọn Heberu ti o wà lọdọ awọn Filistini nigba atijọ, ti o si ti goke ba wọn lọ si budo lati ilu ti o wà yikakiri, awọn na pẹlu si yipada lati dapọ̀ mọ awọn Israeli ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani. Bẹ̃ gẹgẹ nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o ti pa ara wọn mọ ninu okenla Efraimu gbọ́ pe awọn Filistini sa, awọn na pẹlu tẹle wọn lẹhin kikan ni ijà na. Bẹ̃li Oluwa si gbà Israeli là lọjọ na: ija na si rekọja si Bet-afeni.

I. Sam 14:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan, Jonatani, ọmọ Saulu, wí fún ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí òdìkejì ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.” Ṣugbọn Jonatani kò sọ fún Saulu, baba rẹ̀. Ní àkókò yìí, baba rẹ̀ pàgọ́ ogun rẹ̀ sí abẹ́ igi pomegiranate kan ní Migironi, nítòsí Gibea. Àwọn ọmọ ogun bíi ẹgbẹta (600) wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí ó jẹ́ alufaa tí ó ń wọ ẹ̀wù efodu nígbà náà ni Ahija, ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, tíí ṣe alufaa OLUWA ní Ṣilo. Àwọn ọmọ ogun kò mọ̀ pé Jonatani ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn. Àwọn òkúta ńláńlá meji kan wà ní ọ̀nà kan, tí ó wà ní àfonífojì Mikimaṣi. Pàlàpálá òkúta wọnyi ni Jonatani gbà lọ sí ibùdó ogun àwọn Filistini. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òkúta náà wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ọ̀nà náà. Orúkọ ekinni ń jẹ́ Bosesi, ekeji sì ń jẹ́ Sene. Èyí ekinni wà ní apá àríwá ọ̀nà náà, ó dojú kọ Mikimaṣi. Ekeji sì wà ní apá gúsù, ó dojú kọ Geba. Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.” Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Ohunkohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́ ni kí o ṣe. Mo wà lẹ́yìn rẹ, bí ọkàn rẹ ti rí ni tèmi náà rí.” Jonatani bá dáhùn pé, “Ó dára, a óo rékọjá sọ́hùn-ún, a óo sì fi ara wa han àwọn ará Filistia. Bí wọ́n bá ní kí á dúró kí àwọn tọ̀ wá wá, a óo dúró níbi tí a bá wà, a kò ní lọ sọ́dọ̀ wọn. Ṣugbọn bí wọ́n bá ní kí á máa bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn, a óo tọ̀ wọ́n lọ. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún wa, pé OLUWA ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Nítorí náà, wọ́n fi ara wọn han àwọn ará Filistia. Bí àwọn ara Filistia ti rí wọn, wọ́n ní, “Ẹ wò ó! Àwọn Heberu ń jáde bọ̀ wá láti inú ihò òkúta tí wọ́n farapamọ́ sí.” Wọ́n bá nahùn pe Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀; wọ́n ní, “Ẹ máa gòkè tọ̀ wá bọ̀ níhìn-ín, a óo fi nǹkankan hàn yín.” Jonatani bá wí fún ọdọmọkunrin náà pé, “Tẹ̀lé mi, OLUWA ti fún Israẹli ní ìṣẹ́gun lórí wọn.” Jonatani bá rápálá gun òkè náà, ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Jonatani bá bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará Filistia jà, wọ́n sì ń ṣubú níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣubú ni ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ń pa wọ́n. Ní àkókò tí wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, Jonatani ati ọdọmọkunrin yìí pa nǹkan bí ogún eniyan. Ààrin ibi tí wọ́n ti ja ìjà yìí kò ju nǹkan bí ìdajì sarè oko kan lọ. Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn ará Filistia tí wọ́n wà ní ibùdó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, ati gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ ogun Filistini ati àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n ń digun-jalè wárìrì, ilẹ̀ mì tìtì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo wọn. Àwọn ọmọ ogun Saulu tí wọn ń ṣọ́nà ní Gibea, ní agbègbè Bẹnjamini, rí i tí àwọn ọmọ ogun Filistini ń sá káàkiri. Saulu bá pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ka gbogbo àwọn ọmọ ogun, láti mọ àwọn tí wọ́n jáde kúrò láàrin wọn. Wọ́n bá ka àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì rí i pé Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ kò sí láàrin wọn. Saulu wí fún Ahija, alufaa pé, “Gbé àpótí Ọlọrun wá níhìn-ín.” Nítorí àpótí Ọlọrun ń bá àwọn ọmọ ogun Israẹli lọ ní àkókò náà. Bí Saulu ti ń bá alufaa náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìdàrúdàpọ̀ tí ó wà ninu àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, Saulu wí fún un pé kí ó dáwọ́ dúró. Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sójú ogun náà. Wọ́n bá àwọn ọmọ ogun ninu ìdàrúdàpọ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ara wọn. Àwọn Heberu tí wọ́n ti wà lẹ́yìn àwọn ará Filistia tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì bá wọn lọ sí ibùdó ogun wọn, yipada kúrò lẹ́yìn wọn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n wà pẹlu Saulu ati Jonatani. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti farapamọ́ káàkiri agbègbè olókè Efuraimu gbọ́ pé àwọn ará Filistia ti bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ; wọ́n yára dara pọ̀ mọ́ Saulu, wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ọmọ ogun Filistini. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì ja ogun náà kọjá Betafeni.

I. Sam 14:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kan, Jonatani ọmọ Saulu wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Filistini tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀. Saulu sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gibeah lábẹ́ igi pomegiranate èyí tí ó wà ní Migroni. Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin (600) sì wà pẹ̀lú rẹ̀, lára wọn ni Ahijah, tí ó wọ efodu. Òun ni ọmọ arákùnrin Ikabodu Ahitubu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, àlùfáà OLúWA ní Ṣilo kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jonatani ti lọ. Ní ọ̀nà tí Jonatani ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Filistini, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkínní sì ń jẹ́ Bosesi, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sene. Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Mikmasi, èkejì sì wà ní gúúsù ní ìhà Gibeah. Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá OLúWA yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di OLúWA lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.” Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú; Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.” Jonatani sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa. Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún wa pé OLúWA ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.” Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.” Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.” Jonatani sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; OLúWA ti fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́.” Jonatani lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Filistini sì ṣubú níwájú Jonatani ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní ìkọlù èkínní yìí, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbègbè tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sáré ilẹ̀. Nígbà náà ni ìbẹ̀rùbojo bá àwọn ọmọ-ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Saulu ní Gibeah ti Benjamini sì rí àwọn ọmọ-ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà. Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wò ó, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀. Saulu sì wí fún Ahijah pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbà náà. Nígbà tí Saulu sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Filistini sì ń pọ̀ síwájú sí. Saulu sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Saulu àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Filistini ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkejì rẹ̀. Àwọn Heberu tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Filistini tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani. Nígbà tí gbogbo àwọn Israẹli tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Efraimu gbọ́ pé àwọn Filistini sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná. Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA sì gba Israẹli ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Beti-Afeni.