I. Sam 13:1-23
I. Sam 13:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
SAULU jọba li ọdun kan; nigbati o si jọba ọdun meji lori Israeli, Saulu si yan ẹgbẹ̃dogun ọmọkunrin fun ara rẹ̀ ni Israeli; ẹgbã si wà lọdọ Saulu ni Mikmaṣi ati li oke-nla Beteli; ẹgbẹrun si wà lọdọ Jonatani ni Gibea ti Benjamini; o si rán awọn enia ti o kù olukuluku si agọ rẹ̀. Jonatani si pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini ti o wà ninu ile olodi ni Geba, awọn Filistini si gbọ́. Saulu fun ipè yi gbogbo ilẹ na ka, wipe, Jẹ ki awọn Heberu gbọ́. Gbogbo Israeli si gbọ́ pe Saulu pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini, Israeli si di irira fun awọn Filistini. Awọn enia na si pejọ lẹhin Saulu lati lọ si Gilgali. Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni. Awọn ọkunrin Israeli si ri pe, nwọn wà ninu ipọnju (nitoripe awọn enia na wà ninu ìhamọ) nigbana ni awọn enia na fi ara pamọ ninu iho, ati ninu panti, ninu apata, ni ibi giga, ati ninu kanga gbigbẹ. Omiran ninu awọn Heberu goke odo Jordani si ilẹ Gadi ati Gileadi. Bi o ṣe ti Saulu, on wà ni Gilgali sibẹ, gbogbo enia na si nwariri lẹhin rẹ̀. O si duro ni ijọ meje, de akoko ti Samueli dá fun u; ṣugbọn Samueli kò wá si Gilgali, awọn enia si tuka kuro li ọdọ rẹ̀. Saulu si wipe, Mu ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na fun mi wá, o si ru ẹbọ sisun na. O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i. Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi. Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na. Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai. Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ. Samueli si dide, o si lọ lati Gilgali si Gibea ti Benjamini. Saulu si ka awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, o jẹ iwọ̀n ẹgbẹta ọkunrin. Saulu, ati Jonatani ọmọ rẹ̀, ati awọn enia na ti o wà lọdọ wọn si joko ni Gibea ti Benjamini, ṣugbọn awọn Filistini do ni Mikmaṣi. Ẹgbẹ awọn onisùmọ̀mi mẹta jade ni ibudo awọn Filistini: ẹgbẹ kan gbà ọ̀na ti Ofra, si ilẹ Ṣuali. Ẹgbẹ kan si gba ọ̀na Bet-horoni: ati ẹgbẹ kan si gbà ọ̀na agbegbe nì ti o kọju si afonifoji Seboimu ti o wà ni iha iju. Kò si alagbẹdẹ ninu gbogbo ilẹ Israeli: nitori ti awọn Filistini wipe, Ki awọn Heberu ki o má ba rọ idà tabi ọ̀kọ. Ṣugbọn gbogbo Israeli a ma tọ̀ awọn Filistini lọ, olukuluku lati pọ́n doje rẹ̀, ati ọ̀kọ rẹ̀, ati ãke rẹ̀, ati ọ̀ṣọ rẹ̀. Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu. Bẹ̃li o si ṣe li ọjọ ijà, ti a kò ri idà, tabi ọ̀kọ lọwọ ẹnikẹni ninu awọn enia ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani; lọdọ Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ li a ri. Awọn ọmọ-ogun Filistini jade lọ si ikọja Mikmaṣi.
I. Sam 13:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Saulu jẹ́ bíi ọmọ ọgbọ̀n ọdún... nígbà tí ó jọba lórí Israẹli. Ó sì wà lórí oyè fún bíi ogoji ọdún. Saulu yan ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Ó fi ẹgbaa (2,000) ninu wọn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Mikimaṣi, ní agbègbè olókè ti Bẹtẹli. Ẹgbẹrun (1,000) yòókù wà lọ́dọ̀ Jonatani, ọmọ rẹ̀, ní Gibea, ní agbègbè ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó bá dá àwọn yòókù pada sí ilé wọn. Jonatani ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini tí wọ́n wà ní Geba; gbogbo àwọn ará Filistia sì gbọ́ nípa rẹ̀. Saulu bá fọn fèrè ogun jákèjádò ilẹ̀ náà, wí pé “Ẹ jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́ èyí.” Gbogbo Israẹli gbọ́ pé Saulu ti ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini ati pé àwọn ọmọ Israẹli ti di ohun ìríra lójú àwọn ará Filistia. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá jáde láti wá darapọ̀ mọ́ Saulu ní Giligali. Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé ilẹ̀ ti ká àwọn mọ́, nítorí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini dùn wọ́n, wọ́n bá ń farapamọ́ káàkiri; àwọn kan sá sinu ihò ilẹ̀, àwọn mìíràn sì sá sinu àpáta, inú ibojì ati inú kànga. Àwọn mìíràn ninu wọn ré odò Jọdani kọjá sí agbègbè Gadi ati Gileadi. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu Saulu sì wà ninu ìbẹ̀rù ńlá. Ọjọ́ meje ni ó fi dúró de Samuẹli, bí Samuẹli ti wí. Ṣugbọn Samuẹli kò wá sí Giligali. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn Saulu. Nítorí náà, Saulu ní kí wọ́n gbé ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia wá fún òun, ó sì rú ẹbọ. Bí ó ti parí rírú ẹbọ sísun náà tán ni Samuẹli dé. Saulu lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?” Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi. Mo wá rò ó wí pé, àwọn ará Filistia tí ń bọ̀ wá gbógun tì mí ní Giligali níhìn-ín, n kò sì tíì wá ojurere OLUWA. Ni mo bá rú ẹbọ sísun.” Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.” Samuẹli kúrò ní Giligali, ó lọ sí Gibea ní Bẹnjamini. Saulu ka àwọn eniyan tí wọ́n kù lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600). Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, pẹlu àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pàgọ́ sí Geba ní agbègbè Bẹnjamini. Àgọ́ ti àwọn ará Filistia wà ní Mikimaṣi. Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà, mẹta ninu ọmọ ogun Filistini jáde láti inú àgọ́ wọn, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Ofira ní agbègbè Ṣuali, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀. Kò sí ẹyọ alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí pé àwọn ará Filistia ti pinnu pé, àwọn kò ní gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti rọ idà ati ọ̀kọ̀ fúnra wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ pọ́n ohun ìtúlẹ̀ wọn ati ọkọ́ ati àáké ati dòjé, wọ́n níláti lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia. Owó díẹ̀ ni àwọn Filistia máa ń gbà, láti bá wọn pọ́n ohun ìtúlẹ̀ ati ọkọ́, wọ́n ń gba ìdámẹ́ta owó ṣekeli láti pọ́n àáké ati láti tún irin tí ó wà lára ohun ìtúlẹ̀ ṣe. Nítorí náà, ní ọjọ́ ogun yìí kò sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ó ní idà tabi ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, àfi Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀. Ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan sì lọ sí ọ̀nà Mikimaṣi.
I. Sam 13:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Saulu sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjìlélógójì. Saulu yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn. Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali. Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́dógún kẹ̀kẹ́, (3,000) ẹgbẹ̀ta (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi. Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i. Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.” Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere OLúWA.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.” Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí OLúWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, OLúWA ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin OLúWA mọ́.” Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta. Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gibeah ti Benjamini, nígbà tí àwọn Filistini dó ní Mikmasi. Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali, òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí Àfonífojì Ṣeboimu tí ó kọjú sí ijù. A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn. Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù. Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n. Àwọn ẹgbẹ́ ogun Filistini sì ti jáde lọ sí ìkọjá Mikmasi.