I. Sam 12:18-25

I. Sam 12:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Nígbà náà ni Samuẹli ké pe OLúWA, OLúWA sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù OLúWA àti Samuẹli púpọ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí OLúWA Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.” Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ OLúWA, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin OLúWA. Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n. Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ OLúWA kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú OLúWA dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀. Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí OLúWA nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́. Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù OLúWA, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín, ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín. Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”