I. Sam 10:1-6

I. Sam 10:1-6 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí: Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’ Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́. Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀.

I. Sam 10:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “OLúWA kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀? Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Ṣelṣa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’ “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì. Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ wọn. “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ̀mí OLúWA yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀.