I. Sam 10:1-16
I. Sam 10:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
SAMUELI si mu igo ororo, o si tu u si i li ori, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si wipe, Kò ṣepe nitoriti Oluwa ti fi ororo yàn ọ li olori ini rẹ̀? Nigbati iwọ ba lọ kuro lọdọ mi loni, iwọ o ri ọkunrin meji li ẹba iboji Rakeli li agbegbe Benjamini, ni Selsa; nwọn o si wi fun ọ pe, Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá: si wõ, baba rẹ ti fi ọran ti kẹtẹkẹtẹ silẹ, o si kọ ominu nitori rẹ wipe, Kili emi o ṣe niti ọmọ mi? Iwọ o si kọja lati ibẹ lọ, iwọ o si de pẹtẹlẹ Tabori, nibẹ li ọkunrin mẹta ti nlọ sọdọ Ọlọrun ni Beteli yio pade rẹ, ọkan yio mu, ọmọ ewurẹ mẹta lọwọ, ekeji yio mu iṣù akara mẹta, ati ẹkẹta yio mu igo ọti-waini. Nwọn o si ki ọ, nwọn o si fi iṣù akara meji fun ọ; iwọ o si gbà a lọwọ wọn. Lẹhin eyini iwọ o wá si oke Ọlọrun, nibiti ẹgbẹ ogun awọn Filistini wà; yio si ṣe, nigbati iwọ ba de ilu na, iwọ o si pade ẹgbẹ woli ti yio ma sọkalẹ lati ibi giga nì wá; nwọn o si ni psalteri, ati tabreti, ati fère, ati harpu niwaju wọn, nwọn o si ma sọtẹlẹ. Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ o si ma ba wọn sọtẹlẹ, iwọ o si di ẹlomiran. Yio si ri bẹ̃, nigbati àmi wọnyi ba de si ọ, ṣe fun ara rẹ ohun gbogbo ti ọwọ́ rẹ ba ri lati ṣe, nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ. Iwọ o si ṣaju mi sọkalẹ lọ si Gilgali, si kiye si i, emi o sọkalẹ tọ ọ wá, lati rubọ sisun, ati lati ru ẹbọ irẹpọ̀: ni ijọ meje ni iwọ o duro, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe han ọ. O si ri bẹ̃ pe, nigbati o yi ẹhin rẹ̀ pada lati lọ kuro lọdọ Samueli, Ọlọrun si fun u li ọkàn miran: gbogbo àmi wọnni si ṣẹ li ọjọ na. Nigbati nwọn si de ibẹ si oke na, si kiye si i, ẹgbẹ awọn woli pade rẹ̀, Ẹmi Ọlọrun si bà le e, on si sọtẹle larin wọn. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ ri pe o nsọtẹlẹ larin awọn woli, awọn enia si nwi fun ara wọn pe, Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu? Ẹnikan lati ibẹ na wá si dahùn, o si wipe, ṣugbọn tani baba wọn? Bẹ̃li o si wà li owe, Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu? Nigbati o sọtẹlẹ tan, o si lọ si ibi giga nì. Arakunrin Saulu kan si wi fun u ati fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Nibo li ẹnyin ti lọ? On si wipe, lati wá awọn kẹtẹkẹtẹ ni: nigbati awa ri pe nwọn kò si nibi kan, awa si tọ Samueli lọ. Arakunrin Saulu na si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ̀ ọ, ohun ti Samueli wi fun ọ. Saulu si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, On ti sọ fun wa dajudaju pe, nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ nã. Ṣugbọn ọ̀ran ijọba ti Samueli sọ, on kò sọ fun u.
I. Sam 10:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí: Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’ Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́. Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀. Nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣe ohunkohun tí ó bá wá sọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ. Máa lọ sí Giligali ṣiwaju mi. N óo wá bá ọ níbẹ̀ láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meje, títí tí n óo fi dé, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.” Yíyí tí Saulu yipada kúrò lọ́dọ̀ Samuẹli, Ọlọrun sọ ọ́ di ẹ̀dá titun. Gbogbo àwọn àmì tí Samuẹli sọ fún un patapata ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà. Nígbà tí Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ dé Gibea, ọ̀wọ́ àwọn wolii kan pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ láàrin wọn. Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?” Ọkunrin kan tí ń gbé ibẹ̀ bèèrè pé, “Ta ni baba àwọn wolii wọnyi?” Láti ìgbà náà ni ó ti di àṣà kí àwọn eniyan máa wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii ni?” Lẹ́yìn tí Saulu ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, ó lọ sí ibi pẹpẹ, ní orí òkè. Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?” Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.” Arakunrin baba Saulu bá bi í pé, “Kí ni Samuẹli sọ fun yín?” Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba.
I. Sam 10:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “OLúWA kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀? Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Ṣelṣa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’ “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì. Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ wọn. “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ̀mí OLúWA yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀. Bí ìwọ bá ti rí ààmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ. “Lọ ṣáájú mi sí Gilgali. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.” Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo ààmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà. Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi yìí. Ṣé Saulu wà lára àwọn wòlíì ni?” Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń pa òwe pé, ǹjẹ́ Saulu náà wà lára àwọn wòlíì bí? Lẹ́yìn tí Saulu dákẹ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga. Nísinsin yìí, arákùnrin baba Saulu béèrè lọ́wọ́ Saulu àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?” Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli. Arákùnrin baba Saulu wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Samuẹli wí fún un yín.” Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ.