I. Sam 1:9-11
I. Sam 1:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa. On si wà ninu ibinujẹ ọkàn, o si mbẹ Oluwa, o si sọkun gidigidi. On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.
I. Sam 1:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA. Inú Hana bàjẹ́ gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura sí OLUWA, ó sì ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.”
I. Sam 1:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú OLúWA. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé OLúWA ní ibi tí ó máa ń jókòó. Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí OLúWA. Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “OLúWA àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún OLúWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”