I. Sam 1:1-10

I. Sam 1:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin kan wà ninu ẹ̀yà Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikana, ará Ramataimu-sofimu, ní agbègbè olókè Efuraimu. Orúkọ baba rẹ̀ ni Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, láti ìdílé Sufu, ará Efuraimu. Iyawo meji ni Elikana yìí ní. Ọ̀kan ń jẹ́ Hana, ekeji sì ń jẹ́ Penina. Penina bímọ, ṣugbọn Hana kò bí. Ní ọdọọdún ni Elikana máa ń ti Ramataimu-sofimu lọ sí Ṣilo láti lọ sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati láti rúbọ sí i. Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli, ni alufaa OLUWA níbẹ̀. Ní ọjọ́ tí Elikana bá rú ẹbọ rẹ̀, a máa fún Penina ní ìdá kan ninu nǹkan tí ó bá fi rúbọ, a sì máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin ní ìdá kọ̀ọ̀kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ràn Hana, sibẹ ìdá kan ní í máa ń fún un, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí. Penina, orogún Hana, a máa fín in níràn gidigidi, kí ó baà lè mú un bínú, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí. Ní ọdọọdún tí wọ́n bá ti lọ sí ilé OLUWA ni Penina máa ń mú Hana bínú tóbẹ́ẹ̀ tí Hana fi máa ń sọkún, tí kò sì ní jẹun. Ọkọ rẹ̀ a máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, a máa bi í pé, “Kí ní ń pa ọ́ lẹ́kún? Kí ló dé tí o kò jẹun? Kí ní ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ṣé n kò wá ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ ni?” Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA. Inú Hana bàjẹ́ gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura sí OLUWA, ó sì ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

I. Sam 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọkùnrin kan wà, láti Ramataimu-Sofimu, láti ìlú olókè Efraimu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata. Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní. Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí OLúWA àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà OLúWA. Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé OLúWA ti sé e nínú. Nítorí pé OLúWA ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú. Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé OLúWA, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun. Elkana ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hana èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú OLúWA. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé OLúWA ní ibi tí ó máa ń jókòó. Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí OLúWA.