I. Pet 4:1-4
I. Pet 4:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ; Ki ẹnyin ki o máṣe fi ìgba aiye nyin iyokù wà ninu ara mọ́ si ifẹkufẹ enia, bikoṣe si ifẹ Ọlọrun. Nitori igba ti o ti kọja ti to fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrìn ninu iwa wọ̀bia, ifẹkufẹ, ọti amupara, ìrède oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ìbọriṣa ti iṣe ohun irira. Eyi ti o yà wọn lẹnu pe ẹnyin kò ba wọn súré sinu iru aṣejù iwa wọbia wọn, ti nwọn sì nsọrọ nyin ni buburu
I. Pet 4:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Kristi ti jìyà ninu ara, kí ẹ̀yin náà di ọkàn yín ní àmùrè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá jìyà nípa ti ara ti bọ́ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀. Má tún máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀dá mọ́, ṣugbọn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun ninu gbogbo ìgbé-ayé rẹ tí ó kù. Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀. Nisinsinyii ó jẹ́ ohun ìjọjú fún àwọn ẹlẹgbẹ́ yín àtijọ́, nígbà tí ẹ kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọn óo wá máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà.
I. Pet 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀; Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra. Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.