I. Pet 2:21-24
I. Pet 2:21-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀: Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀: Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ: Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada.
I. Pet 2:21-24 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun. Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí. Nígbà tí àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, kò désì pada; wọ́n jẹ ẹ́ níyà, kò ṣe ìlérí ẹ̀san, ṣugbọn ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé Onídàájọ́ òdodo lọ́wọ́. Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.
I. Pet 2:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀: “Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.” Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́. Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá.