I. Pet 1:22-23
I. Pet 1:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá. Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.
I. Pet 1:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín. A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí.
I. Pet 1:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró.