I. A. Ọba 8:12-21

I. A. Ọba 8:12-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Solomoni sọ pe: Oluwa ti wi pe, on o mã gbe inu okùnkun biribiri. Nitõtọ emi ti kọ́ ile kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀, ibukojo kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀ titi lai. Ọba si yi oju rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ enia Israeli: gbogbo ijọ enia Israeli si dide duro; O si wipe, Ibukún ni fun Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ fun Dafidi, baba mi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ mu u ṣẹ, wipe, Lati ọjọ ti emi ti mu Israeli, awọn enia mi jade kuro ni Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹyà Israeli lati kọ́ ile kan, ki orukọ mi ki o le mã gbe inu rẹ̀: ṣugbọn emi yàn Dafidi ṣe olori Israeli, awọn enia mi. O si wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli. Oluwa si wi fun Dafidi baba mi pe, Bi o tijẹpe o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile kan fun orukọ mi, iwọ ṣe rere ti o fi wà li ọkàn rẹ. Ṣibẹ̀ iwọ kì yio kọ́ ile na, ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio ti inu rẹ jade, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. Oluwa si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ, emi si dide ni ipò Dafidi, baba mi, mo si joko lori itẹ́ Israeli, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, emi si kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli. Emi si ti ṣe àye kan nibẹ̀ fun apoti-ẹri, ninu eyiti majẹmu Oluwa gbe wà, ti o ti ba awọn baba wa dá, nigbati o mu wọn jade lati ilẹ Egipti wá.

I. A. Ọba 8:12-21 Yoruba Bible (YCE)

Solomoni bá gbadura, ó ní, “OLUWA, ìwọ ni o fi oòrùn sí ojú ọ̀run, ṣugbọn sibẹsibẹ o yàn láti gbé inú ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Nisinsinyii mo ti kọ́ ilé kan tí ó lọ́lá fún ọ, níbi tí o óo máa gbé títí lae.” Solomoni ọba yipada, ó kọjú sí àwọn eniyan níbi tí wọ́n dúró sí, ó sì súre fún wọn. Ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ìlérí tí ó ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ, tí ó ní, ‘Láti ìgbà tí mo ti kó àwọn eniyan mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti, n kò yan ìlú kan ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli pé kí àwọn ọmọ Israẹli kọ́ ilé ìsìn sibẹ, níbi tí wọn óo ti máa sìn mí, ṣugbọn, mo yan Dafidi láti jọba lórí Israẹli, eniyan mi.’ ” Solomoni tún fi kún un pé, “Ó jẹ́ èrò ọkàn baba mi láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ṣugbọn OLUWA sọ fún un pé nítòótọ́, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti kọ́ ilé fún mi, ó sì dára bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé ìsìn náà, ọmọ bíbí rẹ̀ ni yóo kọ́ ọ. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ: mo ti gorí oyè lẹ́yìn Dafidi, baba mi, mo ti jọba ní ilẹ̀ Israẹli bí OLUWA ti ṣèlérí; mo sì ti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Mo ti ṣètò ibìkan ninu ilé náà fún Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, tí tabili òkúta tí wọ́n kọ majẹmu sí wà ninu rẹ̀, majẹmu tí OLUWA bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti.”

I. A. Ọba 8:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Solomoni sì wí pé, “OLúWA ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri; Nítòótọ́, èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.” Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn. Nígbà náà ni ó wí pé: “Ìbùkún ni fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dafidi láti ṣàkóso àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ “Dafidi baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ OLúWA Ọlọ́run Israẹli. Ṣùgbọ́n OLúWA sì wí fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ. Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’ “OLúWA sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dafidi baba mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli báyìí, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú OLúWA tí ó ti bá àwọn baba wa dá, nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.”