I. A. Ọba 7:1-51

I. A. Ọba 7:1-51 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN Solomoni fi ọdun mẹtala kọ́ ile on tikararẹ̀, o si pari gbogbo iṣẹ ile rẹ̀. O kọ́ ile-igbó Lebanoni pẹlu; gigùn rẹ̀ jasi ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ adọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọnwọ, lori ọ̀wọ́ mẹrin opó igi kedari, ati idabu igi kedari lori awọn opó na. A si fi igi kedari tẹ́ ẹ loke lori iyara ti o joko lori ọwọ̀n marunlelogoji, mẹdogun ni ọ̀wọ́. Ferese si wà ni ọ̀wọ́ mẹta, oju si ko oju ni ọ̀na mẹta. Gbogbo ilẹkun ati opó si dọgba ni igun mẹrin; oju si ko oju ni ọ̀na mẹta. O si fi ọwọ̀n ṣe iloro: gigùn rẹ̀ jẹ adọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ ọgbọ̀n igbọnwọ, iloro kan si wà niwaju rẹ̀: ani ọwọ̀n miran, igi itẹsẹ ti o nipọn si mbẹ niwaju wọn. O si ṣe iloro itẹ nibiti yio ma ṣe idajọ, ani iloro idajọ: a si fi igi kedari tẹ ẹ lati iha kan de keji. Ile rẹ̀ nibiti o ngbe, ni agbala lẹhin ile titi de ọ̀dẹdẹ, si jẹ iṣẹ kanna. Solomoni si kọ́ ile fun ọmọbinrin Farao, ti o ni li aya, bi iloro yi. Gbogbo wọnyi jẹ okuta iyebiye gẹgẹ bi iwọn okuta gbigbẹ́, ti a fi ayùn rẹ́ ninu ati lode, ani lati ipilẹ de ibori-oke ile, bẹ̃ si ni lode si apa agbala nla. Ipilẹ na jẹ okuta iyebiye, ani okuta nlanla, okuta igbọnwọ mẹwa, ati okuta igbọnwọ mẹjọ. Ati okuta iyebiye wà loke nipa iwọ̀n okuta ti a gbẹ́, ati igi kedari. Ati agbàla nla yikakiri pẹlu jẹ ọ̀wọ́ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ọ̀wọ́ kan igi idabu ti kedari, ati fun agbala ile Oluwa ti inu lọhun, ati fun iloro ile na. Solomoni ọba si ranṣẹ, o si mu Hiramu lati Tire wá. Ọmọkunrin opó kan ni, lati inu ẹya Naftali, baba rẹ̀ si ṣe ara Tire, alagbẹdẹ idẹ: on si kún fun ọgbọ́n, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ. O si tọ̀ Solomoni ọba wá, o si ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀. O si dà ọwọ̀n idẹ meji, igbọnwọ mejidilogun ni giga ọkọkan: okùn igbọnwọ mejila li o si yi ọkọkan wọn ka. O si ṣe ipari meji ti idẹ didà lati fi soke awọn ọwọ̀n na: giga ipari kan jẹ igbọnwọ marun, ati giga ipari keji jẹ igbọnwọ marun: Ati oniruru iṣẹ, ati ohun wiwun iṣẹ ẹ̀wọn fun awọn ipari ti mbẹ lori awọn ọwọ̀n na; meje fun ipari kan, ati meje fun ipari keji. O si ṣe ọ̀wọn pomegranate ani ọ̀wọ́ meji yikakiri lara iṣẹ àwọn na, lati fi bò awọn ipari ti mbẹ loke: bẹ̃li o si ṣe fun ipari keji. Ati ipari ti mbẹ li oke awọn ọwọ̀n ti mbẹ ni ọ̀dẹdẹ na ti iṣẹ lili, ni igbọnwọ mẹrin. Ati awọn ipari lori ọwọ̀n meji na wà loke: nwọn si sunmọ ibi ti o yọ lara ọwọ̀n ti o wà nibi iṣẹ àwọn: awọn pomegranate jẹ igba ni ọ̀wọ́ yikakiri, lori ipari keji. O si gbe awọn ọwọ̀n na ro ni iloro tempili: o si gbe ọwọ̀n ọ̀tun ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Jakini: o si gbe ọwọ̀n òsi ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Boasi. Lori oke awọn ọwọ̀n na ni iṣẹ lili wà; bẽni iṣẹ ti awọn ọwọ̀n si pari. O si ṣe agbada nla didà igbọnwọ mẹwa lati eti kan de ekeji: o ṣe birikiti, giga rẹ̀ si jẹ igbọnwọ marun: okùn ọgbọ̀n igbọnwọ li o si yi i kakiri. Ati nisalẹ eti rẹ̀ yikakiri kóko wà yi i ka, mẹwa ninu igbọnwọ kan, o yi agbada nla na kakiri: a dà kóko na ni ẹsẹ meji, nigbati a dà a. O duro lori malu mejila, mẹta nwo iha ariwa, mẹta si nwo iwọ-õrun, mẹ̃ta si nwo gusu, mẹta si nwo ila-õrun; agbada nla na si joko lori wọn, gbogbo apa ẹhin wọn si mbẹ ninu. O si nipọn to ibú atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà ẹgbã iwọ̀n Bati. O si ṣe ijoko idẹ mẹwa; igbọnwọ mẹrin ni gigùn ijoko kọkan, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ mẹta ni giga rẹ̀. Iṣẹ awọn ijoko na ri bayi: nwọn ni alafo ọ̀na arin, alafo ọ̀na arin na si wà lagbedemeji ipade eti. Ati lara alafo ọ̀na arin ti mbẹ lagbedemeji ni aworan kiniun, malu, ati awọn kerubu wà; ati lori ipade eti, ijoko kan wà loke: ati labẹ awọn kiniun, ati malu ni iṣẹ ọṣọ́ wà. Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na. Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika. Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ. Iṣẹ ayika-kẹkẹ́ na si dabi iṣẹ kẹkẹ́; igi idalu wọn, ati ibi iho, ati ibi ipade, ati abukala wọn, didà ni gbogbo wọn. Ifẹsẹtẹ mẹrin li o wà fun igun mẹrin ijoko na: ifẹsẹtẹ na si jẹ ti ijoko tikararẹ̀ papã. Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna. Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri. Gẹgẹ bayi li o si ṣe awọn ijoko mẹwẹwa: gbogbo wọn li o si ni didà kanna, iwọ̀n kanna ati titobi kanna. O si ṣe agbada idẹ mẹwa: agbada kan gbà to òji iwọn Bati: agbada kọ̃kan si jẹ igbọnwọ mẹrin: lori ọkọ̃kan ijoko mẹwẹwa na ni agbada kọ̃kan wà. O si fi ijoko marun si apa ọtún ile na, ati marun si apa òsi ile na: o si gbe agbada-nla ka apa ọ̀tún ile na, si apa ila-õrun si idojukọ gusu: Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba: Ọwọ̀n meji, ati ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n meji; ati iṣẹ àwọ̀n meji lati bò ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n; Ati irinwo pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n meji, ọ̀wọ́ meji pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n kan, lati bò awọn ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n; Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na. Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ agbada nla. Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan. Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ ti mbẹ lagbedemeji Sukkoti on Sartani. Solomoni si jọwọ gbogbo ohun-elo na silẹ li alaiwọ̀n, nitori ti nwọn papọju: bẹ̃ni a kò si mọ̀ iwọ̀n idẹ na. Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Oluwa: pẹpẹ wura, ati tabili wura, lori eyi ti akara ifihan gbe wà. Ati ọpa fitila wura daradara, marun li apa ọtún ati marun li apa òsi, niwaju ibi mimọ́-julọ, pẹlu itanna eweko, ati fitila, ati ẹ̀mú wura. Ati ọpọ́n, ati alumagaji-fitila, ati awo-koto, ati ṣibi, ati awo turari ti wura daradara; ati agbekọ wura, fun ilẹkun inu ile, ibi mimọ́-julọ, ati fun ilẹkun ile na, ani ti tempili. Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ọba ṣe fun ile Oluwa pari. Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá; fadaka, ati wura, ati ohun-elo, o si fi wọn sinu iṣura ile Oluwa.

I. A. Ọba 7:1-51 Yoruba Bible (YCE)

Ọdún mẹtala ni Solomoni fi parí kíkọ́ ilé ti ara rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ilé tí ó kọ́ sí ààfin náà ni Ilé Igbó Lẹbanoni. Ilé náà gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ó sì ga ní ọgbọ̀n igbọnwọ. Orí òpó igi kedari, tí wọ́n na ọ̀pá àjà igi kedari lé, ni wọ́n kọ́ ọ lé. Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí. Ìlà mẹta mẹta ni wọ́n to fèrèsé sí, àwọn fèrèsé ilé náà kọjú sí ara wọn ní àgbékà mẹta. Onígun mẹrin ni wọ́n ṣe férémù tí wọ́n fi ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà ati fèrèsé ilé náà, wọ́n to àwọn fèrèsé ní ìlà mẹta mẹta ninu ògiri, ni àgbékà àgbékà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji ilé náà; wọ́n dojú kọ ara wọn. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó sọ ní gbọ̀ngàn Olópòó. Gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Ó ní ìloro kan tí wọ́n kọ́ sórí òpó; wọ́n ta nǹkan bò ó lórí. Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀. Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo. Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà. Òkúta ńláńlá, olówó ńláńlá, onígbọ̀nwọ́ mẹjọ ati onígbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà. Òkúta olówó ńlá tí a wọ̀n kí á tó gé e, ati igi kedari, ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀. Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé. Solomoni ọba ranṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Huramu wá láti Tire, ará Tire ni baba rẹ̀, ṣugbọn opó ọmọ ẹ̀yà Nafutali kan ni ìyá rẹ̀. Baba rẹ̀ ti jáde láyé, ṣugbọn nígbà ayé rẹ̀, òun náà mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ bàbà dáradára. Huramu gbọ́n, ó lóye, ó sì mọ bí a tíí fi idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Ó tọ Solomoni lọ, ó sì bá a ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. Ó fi bàbà ṣe òpó meji; gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, àyíká rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila, ó ní ihò ninu, nínípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìka mẹrin. Bákan náà ni òpó keji. Ó sì rọ ọpọ́n bàbà meji, ó gbé wọn ka orí àwọn òpó náà. Gíga àwọn ọpọ́n náà jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un. Ó fi irin hun àwọ̀n meji fún àwọn ọpọ́n orí mejeeji tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, àwọ̀n kọ̀ọ̀kan fún ọpọ́n orí òpó kọ̀ọ̀kan. Bákan náà ni ó ṣe èso pomegiranate ní ìlà meji, ó fi wọ́n yí iṣẹ́ ọnà àwọ̀n náà po, ó sì fi dárà sí ọpọ́n tí ó wà lórí òpó. Bákan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n orí òpó keji. Wọ́n ṣe ọpọ́n orí òpó inú yàrá àbáwọlé náà bí ìtànná lílì, ó ga ní igbọnwọ mẹrin. Ọpọ́n kọ̀ọ̀kan wà lórí òpó mejeeji, lórí ibi tí ó yọ jáde tí ó rí bìrìkìtì lára àwọn òpó, lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọnà náà. Igba èso pomegiranate ni wọ́n fi yí àwọn òpó náà ká ní ọ̀nà meji. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe sí òpó keji pẹlu. Ó ri àwọn òpó mejeeji yìí sí àbáwọ Tẹmpili, wọ́n ri ọ̀kan sí ìhà gúsù, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jakini; wọ́n ri ekeji sí apá àríwá, wọ́n sì pè é ní Boasi. Iṣẹ́ ọnà ìtànná lílì ni wọ́n ṣe sára àwọn òpó náà. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ṣe parí lórí àwọn òpó náà. Ó ṣe agbada omi rìbìtì kan. Jíjìn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Àyíká rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Wọ́n fi idẹ ṣe ọpọlọpọ agbè, wọ́n tò wọ́n ní ìlà meji sí etí agbada omi náà. Láti ilẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àwọn agbè yìí ní àṣepọ̀ mọ́ agbada omi náà. Wọ́n gbé agbada yìí ka orí akọ mààlúù mejila, tí wọ́n fi bàbà ṣe. Mẹta ninu àwọn mààlúù náà dojú kọ apá ìhà àríwá, àwọn mẹta dojú kọ apá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹta dojú kọ apá gúsù, àwọn mẹta sì dojú kọ apá ìlà oòrùn. Agbada náà nípọn ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Etí rẹ̀ dàbí etí ife omi, ó tẹ̀ ní àtẹ̀sóde bí ìsàlẹ̀ òdòdó lílì. Agbada náà lè gbà tó ẹgbaa (2,000) galọọnu omi. Huramu tún fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n sì ga ní igbọnwọ mẹta. Báyìí ni wọ́n ṣe mọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà: wọ́n ní ìtẹ́dìí, àwọn ìtẹ́dìí yìí sì ní igun mẹrin mẹrin, lórí àwọn ìtẹ́dìí yìí ni ó ya àwòrán àwọn kinniun, mààlúù ati ti kerubu sí. Wọ́n ṣe àwọn ọnà róbótó róbótó kan báyìí sí òkè àwọn kinniun ati akọ mààlúù náà ati sí ìsàlẹ̀ wọn. Olukuluku ìtẹ́lẹ̀ yìí ni ó ní àgbá kẹ̀kẹ́ idẹ mẹrin, igun mẹrẹẹrin rẹ̀ sì ní ìtẹ́lẹ̀, lábẹ́ agbada náà ni àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí a rọ wà. A ṣe ọ̀ṣọ́ sí gbogbo igun ìtẹ́lẹ̀ náà, òkè agbada náà dàbí adé tí a yọ sókè ní igbọnwọ kan, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà yí etí rẹ̀ po. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrẹẹrin wà lábẹ́ àwọn ìtẹ́dìí yìí, àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá inú àgbá kẹ̀kẹ́ náà. Gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó ṣe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yìí bíi ti kẹ̀kẹ́ ogun, dídà ni wọ́n dà á ati irin tí àgbá náà fi ń yí, ati riimu wọn, ati sipoku ati họọbu wọn. Ìtẹ́lẹ̀ mẹrin mẹrin ló wà ní orígun mẹrẹẹrin àwọn ìtẹ́dìí náà, ẹyọ kan náà ni wọ́n ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ pẹlu ìtẹ́dìí yìí. A mọ ìgbátí yíká òkè àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà, tí ó ga sókè ní ààbọ̀ igbọnwọ, ìgbátí yìí wà ní téńté orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe òun ati ìtẹ́dìí rẹ̀. Ó ya àwòrán àwọn kerubu, ati kinniun ati ti igi ọ̀pẹ sí orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ ati ìtẹ́dìí yìí, bí ààyè ti wà fún olukuluku sí; ó sì ṣe òdòdó sí i yípo. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá, bákan náà ni ó da gbogbo wọn, bákan náà ni wọ́n tó, bákan náà ni wọn sì rí. Ó ṣe abọ́ bàbà ńlá mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gba igba galọọnu, ó sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin. Abọ́ kọ̀ọ̀kan sì wà lórí ìtẹ̀lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Ó to ìtẹ́lẹ̀ marun-un marun-un sí apá ìhà gúsù ati apá ìhà àríwá ilé náà, ó sì gbé agbada omi sí igun tí ó wà ní agbedemeji ìhà gúsù ati ìhà ìlà oòrùn ilé náà. Huramu mọ ọpọlọpọ ìkòkò, ó fi irin rọ ọkọ́ pupọ, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó bá Solomoni ọba ṣe ninu ilé OLUWA. Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, ati àwọn ọpọ́n rìbìtì rìbìtì meji tí ó wà lórí àwọn òpó náà, ati iṣẹ́ ọnà tí ó ṣe sí ara àwo meji tí ó wà lórí ọpọ́n. Àwọn irinwo pomegiranate tí wọ́n tò sí ìlà meji yí ọpọ́n bìrìkìtì bìrìkìtì orí àwọn òpó náà ká, ní ọgọọgọrun-un. Ó ṣe agbada omi mẹ́wàá ati ìtẹ́dìí kọ̀ọ̀kan fún wọn. Ó ṣe agbada omi ńlá kan ati àwọn ère mààlúù mejila tí wọ́n wà ní abẹ́ rẹ̀. Bàbà dídán ni Huramu fi ṣe àwọn ìkòkò ati ọkọ́ ati àwokòtò ati gbogbo ohun èlò inú ilé OLUWA tí ó ṣe fún Solomoni ọba. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Saretani, ni ọba ti ṣe wọ́n. Solomoni kò wọn àwọn ohun èlò tí ó ṣe, nítorí wọ́n pọ̀ yanturu. Nítorí náà kò mọ ìwọ̀n bàbà tí ó lò. Solomoni ṣe gbogbo àwọn ohun èlò wọnyi sinu ilé OLUWA: pẹpẹ wúrà, tabili wúrà fún burẹdi ìfihàn; àwọn ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe: marun-un ní ìhà àríwá, ati marun-un ní ìhà gúsù níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ; àwọn òdòdó, àwọn fìtílà, ati àwọn ẹ̀mú wúrà, àwọn ife ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná ẹnu fìtílà; àwokòtò ati àwo turari, àwo ìfọnná tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, wọ́n fi wúrà ṣe àwọn ihò àgbékọ́ ìlẹ̀kùn Ibi-Mímọ́-Jùlọ ati ti ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn Tẹmpili náà. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe parí gbogbo iṣẹ́ kíkọ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò inú ilé ìsìn, tí Dafidi, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ wá, ó sì fi wọ́n pamọ́ sinu àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.

I. A. Ọba 7:1-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Solomoni sì lo ọdún mẹ́tàlá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀. Ó kọ́ ilé igbó Lebanoni pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kedari, àti ìdábùú igi kedari lórí òpó náà. A sì fi igi kedari tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ́n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ọ̀wọ́. Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn. Gbogbo ìlẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn. Ó sì fi ọ̀wọ́n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn. Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kedari bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé. Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Solomoni sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Farao tí ó ní ní aya. Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde. Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńláńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbẹ́ àti igi kedari. Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kedari, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé OLúWA pẹ̀lú ìloro rẹ̀. Solomoni ọba ránṣẹ́ sí Tire, ó sì mú Hiramu wá, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Naftali àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tire, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hiramu sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Solomoni ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un. Ó sì dá ọ̀wọ́n idẹ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún ní gíga okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ni ó sì yí wọn ká. Ó sì túnṣe ìparí méjì ti idẹ dídá láti fi sókè àwọn ọ̀wọ́n náà, ìparí kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga. Onírúurú iṣẹ́, àti ohun híhun ẹ̀wọ̀n fún àwọn ìparí tí ń bẹ lórí àwọn ọ̀wọ́n náà, méje fún ìparí kọ̀ọ̀kan. Ó sì ṣe àwọn pomegiranate ní ọ̀wọ́ méjì yíkákiri lára iṣẹ́ ọ̀wọ́n náà, láti fi bo àwọn ìparí ti ń bẹ lókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìparí kejì. Àwọn ìparí tí ń bẹ ní òkè àwọn ọ̀wọ́n náà tí ń bẹ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà dàbí àwòrán lílì, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga. Lórí àwọn ìparí ọ̀wọ́n méjì náà lókè, wọ́n sì súnmọ́ ibi tí ó yẹ lára ọ̀wọ́n tí ó wà níbi iṣẹ́ ọ̀wọ́n, wọ́n sì jẹ́ igba (200) pomegiranate ní ọ̀wọ́ yíkákiri. Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹmpili, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ́n tí ó wà ní gúúsù ní Jakini àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Boasi. Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ́n sì parí. Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ́n yí i ká. Ní ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wá yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a. Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà-oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú. Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbàá (2,000) ìwọ̀n bati. Ó sì túnṣe ẹsẹ̀ idẹ tí a lè gbé mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga. Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà: Wọ́n ní àlàfo ọnà àárín tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí. Lórí àlàfo ọnà àárín tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà. Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀. Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà. Àlàfo ọ̀nà àárín ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká. Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárín, a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà. Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. A sì ṣe àyíká kẹ̀kẹ́ náà bí i iṣẹ́ kẹ̀kẹ́; igi ìdálu, ibi ihò, ibi ìpàdé, àti ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, gbogbo wọn sì jẹ́ irin dídà. Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹsẹ̀. Lókè ẹsẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárín rẹ̀ ni a so mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà. Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ, sára ìgbátí rẹ̀ àti sára pákó tí ó gbé ró, ní gbogbo ibi tí ààyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri. Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà. Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà. Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn-ún sí apá ọ̀tún ìhà gúúsù ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà-oòrùn sí ìdojúkọ gúúsù ilé náà. Ó sì túnṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwokòtò. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé OLúWA fún Solomoni ọba: Àwọn ọ̀wọ́n méjì; Ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́; àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n; Irínwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n; Ẹsẹ̀ mẹ́wàá pẹ̀lú agbádá mẹ́wàá wọn; Agbada ńlá náà, àti màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀; Ìkòkò, ọkọ́ àti àwokòtò. Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hiramu ṣe fún Solomoni ọba nítorí iṣẹ́ OLúWA sì jẹ́ idẹ dídán. Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani lágbedeméjì Sukkoti àti Saretani. Solomoni sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ́n, nítorí tí wọ́n pọ̀jù; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ. Solomoni sì túnṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé OLúWA pẹ̀lú: pẹpẹ wúrà; tábìlì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà; Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn-ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko; fìtílà àti ẹ̀mú wúrà; Ọpọ́n kìkì wúrà, alumagaji fìtílà, àti àwokòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára; àti àgbékọ́ wúrà fún ìlẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ìlẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹmpili. Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLúWA parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé OLúWA.