I. A. Ọba 6:1-18
I. A. Ọba 6:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, ni ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹ̀rẹ si ikọ́ ile fun Oluwa. Ile na ti Solomoni ọba kọ́ fun Oluwa, gigun rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ibú rẹ̀, ogun igbọnwọ, ati giga rẹ̀, ọgbọn igbọnwọ. Ati ọ̀dẹdẹ niwaju tempili ile na, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, gẹgẹ bi ibú ile na: igbọnwọ mẹwa si ni ibú rẹ̀ niwaju ile na. Ati fun ile na ni a ṣe ferese fun síse. Lara ogiri ile na li o bù yàra yika; ati tempili, ati ibi-mimọ́-julọ, li o si ṣe yara yika. Yara isalẹ, igbọnwọ marun ni gbigbòro rẹ̀, ti ãrin, igbọnwọ mẹfa ni gbigbòro rẹ̀, ati ẹkẹta, igbọnwọ meje ni gbigbòro rẹ̀, nitori lode ogiri ile na li o dín igbọnwọ kọ̃kan kakiri, ki igi-àja ki o má ba wọ inu ogiri ile na. Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ. Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta. Bẹ̃li o kọ́ ile na, ti o si pari rẹ̀: o si fi gbelerù ati apako kedari bò ile na. O si kọ́ yara gbè gbogbo ile na, igbọnwọ marun ni giga: o fi ìti kedari mú wọn fi ara ti ile na. Ọ̀rọ Oluwa si tọ Solomoni wá wipe, Nipa ti ile yi ti iwọ nkọ́ lọwọ nì, bi iwọ o ba rin ninu aṣẹ mi, ti iwọ o si ṣe idajọ mi, ati ti iwọ o si pa gbogbo ofin mi mọ lati ma rin ninu wọn, nigbana ni emi o mu ọ̀rọ mi ṣẹ pẹlu rẹ, ti mo ti sọ fun Dafidi, baba rẹ; Emi o si ma gbe ãrin awọn ọmọ Israeli, emi kì o si kọ̀ Israeli, enia mi. Solomoni si kọ́ ile na, o si pari rẹ̀. O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na. O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ. Ati ile na, eyini ni Tempili niwaju rẹ̀, jẹ ogoji igbọnwọ ni gigùn. Ati kedari ile na ninu ile li a fi irudi ati itanna ṣe iṣẹ ọnà rẹ̀: gbogbo rẹ̀ kiki igi kedari; a kò ri okuta kan.
I. A. Ọba 6:1-18 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ọrinlenirinwo (480) ọdún tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ní ọdún kẹrin tí Solomoni gun orí oyè ní Israẹli, ní oṣù Sifi, tíí ṣe oṣù keji ọdún náà, ni ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé OLUWA. Gígùn ilé tí Solomoni kọ́ fún OLUWA jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Yàrá àbáwọlé ilé ìsìn náà gùn ní ogún igbọnwọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé pẹlu ìbú rẹ̀, ó sì jìn sí ìsàlẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá níwájú. Ògiri ilé ìsìn náà ní àwọn fèrèsé tí wọ́n fẹ̀ ninu ju bí wọ́n ti fẹ̀ lóde lọ. Wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta mọ́ ara ògiri ilé ìsìn náà yípo lọ́wọ́ òde, ati gbọ̀ngàn ti òde, ati ibi mímọ́ ti inú; wọ́n sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ sí i yípo. Gíga àgbékà kọ̀ọ̀kan ilé náà jẹ́ igbọnwọ marun-un; ilé ti ìsàlẹ̀ fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un; àgbékà ti ààrin fẹ̀ ní igbọnwọ mẹfa, àgbékà ti òkè patapata fẹ̀ ní igbọnwọ meje. Ògiri àgbékà tí ó wà ní òkè patapata kò nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ààrin, ti ààrin kò sì nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata; tí ó fi jẹ́ pé àwọn yàrá náà lè jókòó lórí ògiri láìfi òpó gbé wọn ró. Níbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta ni wọ́n ti gbẹ́ gbogbo òkúta tí wọ́n fi kọ́ ilé ìsìn náà, wọn kò lo òòlù, tabi àáké, tabi ohun èlò irin kankan ninu tẹmpili náà nígbà tí wọ́n ti ń kọ́ ọ lọ. Ninu ilé alágbèékà mẹta tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ìsìn náà, ẹnu ọ̀nà ilé tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata wà ní apá gúsù ilé ìsìn náà, ó ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà keji, àgbékà keji sì ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe kọ́ ilé ìsìn náà parí, ó sì fi ọ̀pá àjà ati pákó igi kedari ṣe àjà rẹ̀. Ara ògiri ilé ìsìn náà níta ni wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta yìí mọ́, àgbékà kọ̀ọ̀kan ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n sì fi pákó igi kedari so wọ́n pọ̀ mọ́ ara ilé ìsìn náà. OLUWA wí fún Solomoni ọba pé, “Ní ti ilé ìsìn tí ò ń kọ́ yìí, bí o bá pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o sì tẹ̀lé ìlànà mi, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, fún ọ. N óo máa gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli, n kò sì ní kọ eniyan mi sílẹ̀ laelae.” Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí kíkọ́ ilé ìsìn náà. Pákó igi kedari ni ó fi bo ara ògiri ilé náà ninu, láti òkè dé ilẹ̀. Pákó igi sipirẹsi ni wọ́n sì fi tẹ́ gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. Wọ́n kọ́ yàrá kan tí wọn ń pè ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, pákó kedari ni wọn fi gé e láti òkè dé ilẹ̀. Gbọ̀ngàn tí ó wà níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ yìí gùn ní ogoji igbọnwọ. Wọ́n gbẹ́ àwòrán agbè ati òdòdó, wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sára igi kedari tí wọ́n fi bo ògiri gbọ̀ngàn náà, òkúta tí wọ́n fi mọ ògiri ilé náà kò sì hàn síta rárá.
I. A. Ọba 6:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLúWA. Ilé náà tí Solomoni ọba kọ́ fún OLúWA sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ìloro níwájú tẹmpili ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà. Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà. Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká; àti tẹmpili àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká. Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ti àárín sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀. Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ̀ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà. Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́. Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìsàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúúsù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárín, àti láti yàrá àárín bọ́ sínú ẹ̀kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó kedari. Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi kedari. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Solomoni wá wí pé, “Ní ti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀. Èmi yóò sì máa gbé àárín àwọn ọmọ Israẹli, èmi kì ó sì kọ Israẹli ènìyàn mi.” Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀. Ó sì fi pákó kedari tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó firi tẹ́ ilẹ̀ ilé náà. Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kedari kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ní iwájú ilé náà, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́. Inú ilé náà sì jẹ́ kedari, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ kedari; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.