I. A. Ọba 5:14 - Compare All Versions

I. A. Ọba 5:14 YBCV (Bibeli Mimọ)

O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na.

I. A. Ọba 5:14 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.

I. A. Ọba 5:14 YCE (Yoruba Bible)

Ó fi Adoniramu ṣe alabojuto wọn. Ó pín wọn sí ọ̀nà mẹta: ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ní ìpín kọ̀ọ̀kan. Ìpín kọ̀ọ̀kan a máa ṣiṣẹ́ fún oṣù kan ní Lẹbanoni, wọn á sì pada sílé fún oṣù meji.