I. A. Ọba 4:1-19
I. A. Ọba 4:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
SOLOMONI ọba si jẹ ọba lori gbogbo Israeli. Awọn wọnyi ni awọn ijoye ti o ni; Asariah, ọmọ Sadoku alufa, Elihorefu ati Ahiah, awọn ọmọ Ṣiṣa li akọwe, Jehoṣafati ọmọ Ahiludi li akọwe ilu. Ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, li olori-ogun: ati Sadoku ati Abiatari ni awọn alufa: Ati Asariah, ọmọ Natani, li olori awọn ọgagun: Sabudu, ọmọ Natani, alufa, si ni ọrẹ ọba: Ati Ahiṣari li o ṣe olori agbo-ile: ati Adoniramu, ọmọ Abda li o nṣe olori iṣẹ-irú. Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese. Orukọ wọn si ni wọnyi: Benhuri li oke Efraimu. Bendekari ni Makasi, ati ni Ṣaalbimu ati Betṣemeṣi, ati Elonibethanani: Benhesedi, ni Aruboti; tirẹ̀ ni Soko iṣe ati gbogbo ilẹ Heferi: Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya. Baana ọmọ Ahiludi, tirẹ̀ ni Taanaki iṣe, ati Megiddo, ati gbogbo Betṣeani ti mbẹ niha Sartana nisalẹ Jesreeli, lati Betṣeani de Abelmehola, ani titi de ibi ti mbẹ ni ikọja Jokneamu; Ọmọ Geberi ni Ramoti-Gileadi; tirẹ̀ ni awọn ileto Jairi, ọmọ Manasse, ti mbẹ ni Gileadi; tirẹ̀ si ni apa Argobu, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu ti o tobi, ti o li odi ati ọpa-idabu idẹ. Ahinadabu, ọmọ Iddo, li o ni Mahanaimu. Ahimaasi wà ni Naftali; on pẹlu li o ni Basmati, ọmọbinrin Solomoni, li aya. Baana, ọmọ Huṣai wà ni Aṣeri ati ni Aloti. Jehoṣafati, ọmọ Paruha, ni Issakari: Ṣimei, ọmọ Ela, ni Benjamini. Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na.
I. A. Ọba 4:1-19 Yoruba Bible (YCE)
Solomoni jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli, Orúkọ àwọn olórí ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Asaraya, ọmọ Sadoku ni alufaa. Elihorefi ati Ahija, meji ninu àwọn ọmọ Ṣiṣa ni akọ̀wé ní ààfin ọba. Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn ìwé àkọsílẹ̀. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ni balogun. Sadoku ati Abiatari jẹ́ alufaa, Asaraya, ọmọ Natani, ni olórí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́. Sabudu, ọmọ Natani, ni alufaa ati olùdámọ̀ràn fún ọba. Ahiṣari ni olùdarí gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ààfin. Adoniramu ọmọ Abida ni olórí àwọn tí ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá. Solomoni yan àwọn mejila gẹ́gẹ́ bí alákòóso ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ni wọ́n ń ṣe ètò àtikó oúnjẹ jọ ní agbègbè wọn, fún ìtọ́jú ọba ati gbogbo àwọn tí ń gbé ààfin ọba. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn á máa pèsè oúnjẹ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ninu ọdún kọ̀ọ̀kan. Orúkọ àwọn alákòóso mejeejila ati agbègbè tí olukuluku wọn ń mójú tó nìwọ̀nyí: Benhuri ní ń ṣe àkóso agbègbè olókè Efuraimu; Bẹndekeri ni alákòóso fún ìlú Makasi, ati Ṣaalibimu, ìlú Beti Ṣemeṣi, Eloni, ati Beti Hanani. Benhesedi ní Aruboti ni alákòóso fún ìlú Aruboti, ati Soko, ati gbogbo agbègbè Heferi. Bẹnabinadabu, ọkọ Tafati, ọmọ Solomoni, ni alákòóso gbogbo agbègbè Nafati-dori. Baana, ọmọ Ahiludi, ni alákòóso ìlú Taanaki, ati ti Megido, ati gbogbo agbègbè Beti Ṣeani, lẹ́bàá ìlú Saretani, ní ìhà gúsù Jesireeli ati Beti Ṣeani; títí dé ìlú Abeli Mehola títí dé òdìkejì Jokimeamu. Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.) Ahinadabu, ọmọ Ido ni alákòóso agbègbè Mahanaimu. Ahimaasi, (ọkọ Basemati, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Solomoni), ni alákòóso Nafutali. Baana, ọmọ Huṣai, ni alákòóso agbègbè Aṣeri, ati Bealoti. Jehoṣafati, ọmọ Parua, ni alákòóso agbègbè Isakari. Ṣimei, ọmọ Ela, ni alákòóso agbègbè Bẹnjamini. Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda.
I. A. Ọba 4:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Solomoni ọba sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀: Asariah ọmọ Sadoku àlùfáà: Elihorefu àti Ahijah àwọn ọmọ Ṣisa akọ̀wé; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọ̀wé ìlú; Benaiah ọmọ Jehoiada ni olórí ogun; Sadoku àti Abiatari ni àwọn àlùfáà; Asariah ọmọ Natani ni olórí àwọn agbègbè; Sobudu ọmọ Natani, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn; Ahiṣari ni olùtọ́jú ààfin; Adoniramu ọmọ Abida ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú. Solomoni sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbègbè Israẹli, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún. Orúkọ wọn ni wọ̀nyí: Bene-Huri ní ìlú olókè Efraimu. Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani; Bene-Hesedi, ní Aruboti; tirẹ̀ ni Soko àti gbogbo ilẹ̀ Heferi ń ṣe; Bene-Abinadabu, ní Napoti Dori; òun ni ó fẹ́ Tafati ọmọbìnrin Solomoni ní aya. Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu; Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi; tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta (60) ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin. Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu Ahimasi ní Naftali; ó fẹ́ Basemati ọmọbìnrin Solomoni ní aya; Baana ọmọ Huṣai ní Aṣeri àti ní Aloti; Jehoṣafati ọmọ Parua ni ó wà ní Isakari; Ṣimei ọmọ Ela ni Benjamini; Geberi ọmọ Uri ní Gileadi; orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani. Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.