I. A. Ọba 22:29-40

I. A. Ọba 22:29-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, goke lọ si Ramoti-Gileadi. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà. Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan. O si ṣe, bi awọn olori-kẹkẹ́ ti ri Jehoṣafati, nwọn si wipe, ọba Israeli li eyi. Nwọn si yà sapakan lati ba a jà: Jehoṣafati si kigbe. O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ woye pe, kì iṣe ọba Israeli li eyi, nwọn si pada kuro lẹhin rẹ̀. Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ. Ogun na si le li ọjọ na: a si dá ọba duro ninu kẹkẹ́ kọju si awọn ara Siria, o si kú li aṣalẹ, ẹ̀jẹ si ṣàn jade lati inu ọgbẹ na si ãrin kẹkẹ́ na. A si kede la ibudo já li akokò iwọ̀ õrun wipe, Olukuluku si ilu rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀. Bẹ̃ni ọba kú, a si gbe e wá si Samaria; nwọn si sin ọba ni Samaria. Ẹnikan si wẹ kẹkẹ́ na ni adagun Samaria, awọn ajá si la ẹ̀jẹ rẹ̀; awọn àgbere si wẹ ara wọn ninu rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ, Ati iyokù iṣe Ahabu, ati gbogbo eyi ti o ṣe, ati ile ehin-erin ti o kọ́, ati gbogbo ilu ti o tẹ̀do, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Ahabu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Ahasiah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

I. A. Ọba 22:29-40 Yoruba Bible (YCE)

Ahabu, ọba Israẹli, ati Jehoṣafati, ọba Juda, bá lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sí ojú ogun yìí, n óo paradà, kí ẹnikẹ́ni má baà dá mi mọ̀. Ṣugbọn ìwọ, wọ aṣọ oyè rẹ.” Ahabu, ọba Israẹli, bá paradà, ó sì lọ sójú ogun. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ mejeejilelọgbọn, pé kí wọ́n má lépa ẹnikẹ́ni lójú ogun, àfi ọba Israẹli nìkan. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati ọba, wọ́n ní, “Dájúdájú ọba Israẹli nìyí.” Wọ́n bá yipada láti bá a jà; ṣugbọn Jehoṣafati kígbe. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe òun ni ọba Israẹli, wọ́n bá pada lẹ́yìn rẹ̀. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́. Ogun gbóná gidigidi ní ọjọ́ náà. Ọwọ́ ni wọ́n fi ti ọba Ahabu ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà, tí ó sì kọjú sí àwọn ará Siria. Nígbà tí yóo sì fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn láti ojú ọgbẹ́ rẹ̀ sì ti dà sí ìsàlẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun náà. Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, wọ́n kéde fún gbogbo àwọn ọmọ ogun pé, “Kí olukuluku pada sí agbègbè rẹ̀! Kí kaluku kọrí sí ìlú rẹ̀!” Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ọba ṣe kú; wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí Samaria, wọ́n sì sin ín sibẹ. Wọ́n lọ fọ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní adágún Samaria, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì lọ wẹ̀ ninu adágún náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóo rí. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Ahabu ọba ṣe, ati àkọsílẹ̀ bí ó ṣe fi eyín erin ṣe iṣẹ́ ọnà sí ààfin rẹ̀, ati ti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Lẹ́yìn tí òun kú ni Ahasaya ọmọ rẹ̀ gun orí oyè.

I. A. Ọba 22:29-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda gòkè lọ sí Ramoti Gileadi. Ọba Israẹli sì wí fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. Ọba Aramu ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, “Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Israẹli nìkan.” Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jehoṣafati, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Israẹli ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jehoṣafati sì kígbe sókè, àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Israẹli sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.” Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Aramu. Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárín kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́. A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀-oòrùn wí pé, “Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!” Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samaria, wọ́n sì sin ín ní Samaria. Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samaria, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn àgbèrè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA ti sọ. Ní ti ìyókù ìṣe Ahabu, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ilé eyín erin tí ó kọ́, àti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Ahabu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Ahasiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.