I. A. Ọba 21:1-29

I. A. Ọba 21:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, Naboti, ara Jesreeli, ni ọgba-ajara ti o wà ni Jesreeli, ti o sunmọ ãfin Ahabu, ọba Samaria girigiri. Ahabu si ba Naboti sọ wipe, Fun mi ni ọgba-ajara rẹ, ki emi ki o fi ṣe ọgba-ewebẹ̀, nitori ti o sunmọ ile mi: emi o si fun ọ li ọgba-ajara ti o san jù u lọ dipò rẹ̀; bi o ba si dara li oju rẹ, emi o fi iye-owo rẹ̀ fun ọ. Naboti si wi fun Ahabu pe, Oluwa má jẹ ki emi fi ogún awọn baba mi fun ọ. Ahabu si wá si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ nitori ọ̀rọ ti Naboti, ara Jesreeli, sọ fun u: nitoriti on ti wipe, emi kì o fun ọ ni ogún awọn baba mi. On si dubulẹ lori akete rẹ̀, o si yi oju rẹ̀ padà, kò si fẹ ijẹun. Jesebeli, aya rẹ̀ si tọ̀ ọ wá o si wi fun u pe, Ẽṣe ti inu rẹ fi bajẹ́ ti iwọ kò fi jẹun? O si wi fun u pe, Nitoriti mo ba Naboti, ara Jesreeli sọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni ọgba-àjara rẹ fun owo; tabi bi o ba wù ọ, emi o fun ọ ni ọgba-àjara miran ni ipò rẹ̀: o si dahùn wipe, Emi kì o fun ọ ni ọgba-àjara mi. Jesebeli, aya rẹ̀ si wi fun u pe, iwọ kò ha jọba lori Israeli nisisiyi? Dide, jẹun, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn! emi o fun ọ ni ọgba-àjara Nãboti ara Jesreeli. Bẹ̃ni o kọwe li orukọ Ahabu, o si fi èdidi rẹ̀ di i, o si fi iwe na ṣọwọ sọdọ awọn àgbagba ati awọn ọlọla ti mbẹ ni ilu rẹ̀, ti o si mba Naboti gbe. O si kọ sinu iwe na pe, Ẹ kede àwẹ, ki ẹ si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia. Ki ẹ fi enia meji, ẹni buburu, siwaju rẹ̀ lati jẹri pa a, wipe, Iwọ bu Ọlọrun ati ọba. Ẹ mu u jade, ki ẹ si sọ ọ li okuta ki o le kú. Awọn ọkunrin ilu rẹ̀, ati awọn àgbagba, ati awọn ọlọla ti nwọn iṣe ara-ilu rẹ̀, ṣe bi Jesebeli ti ranṣẹ si wọn, gẹgẹ bi a ti kọ ọ sinu iwe ti o ti fi ranṣẹ si wọn. Nwọn si kede àwẹ, nwọn si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia. Ọkunrin meji si de, awọn ẹni buburu, nwọn si joko niwaju rẹ̀: awọn ọkunrin buburu si jẹri pa a, ani si Naboti, niwaju awọn enia wipe: Naboti bu Ọlọrun ati ọba. Nigbana ni nwọn mu u jade kuro ni ilu, nwọn si sọ ọ li okuta, o si kú. Nigbana ni nwọn ranṣẹ si Jesebeli wipe, A sọ Naboti li okuta, o si kú. O si ṣe, nigbati Jesebeli gbọ́ pe, a sọ Naboti li okuta, o si kú, Jesebeli sọ fun Ahabu pe, Dide! ki o si jogun ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli, ti o kọ̀ lati fi fun ọ fun owo; nitori Naboti kò si lãye ṣugbọn o kú. O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ pe, Naboti kú, ni Ahabu dide lati sọkalẹ lọ si ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli lati jogun rẹ̀. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe, Dide, sọkalẹ, lọ ipade Ahabu, ọba Israeli, ti o wà ni Samaria: wò o, o wà ni ọgba-ajara Naboti, nibiti o sọkalẹ lọ lati jogun rẹ̀. Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ. Ahabu si wi fun Elijah pe, Iwọ ri mi, Iwọ ọta mi? O si dahùn wipe, Emi ri ọ; nitoriti iwọ ti tà ara rẹ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa. Kiyesi i, Emi o mu ibi wá si ori rẹ, emi o si mu iran rẹ kuro, emi o si ke kuro lọdọ Ahabu, gbogbo ọmọde ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ, ati omnira ni Israeli. Emi o si ṣe ile rẹ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa, ọmọ Ahijah, nitori imunibinu ti iwọ ti mu mi binu, ti iwọ si mu ki Israeli ki o dẹ̀ṣẹ. Ati niti Jesebeli pẹlu Oluwa sọ wipe, Awọn ajá yio jẹ Jesebeli ninu yàra Jesreeli. Ẹni Ahabu ti o kú ni ilu, ni awọn ajá o jẹ; ati ẹniti o kú ni igbẹ ni awọn ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ. Ṣugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rẹ̀ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rẹ̀ ntì. O si ṣe ohun irira gidigidi ni titọ̀ oriṣa lẹhin, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awọn ara Amori ti ṣe, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli. O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si gbàwẹ, o si dubulẹ ninu aṣọ ọ̀fọ, o si nlọ jẹ́. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe, Iwọ ri bi Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi? Nitori ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi, emi kì yio mu ibi na wá li ọjọ rẹ̀: li ọjọ ọmọ rẹ̀ li emi o mu ibi na wá sori ile rẹ̀.

I. A. Ọba 21:1-29 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Naboti, ará Jesireeli, ní ọgbà àjàrà kan. Ní Jesireeli ni ọgbà yìí wà, lẹ́bàá ààfin Ahabu, ọba Samaria. Ní ọjọ́ kan, Ahabu pe Naboti ó ní, “Fún mi ni ọgbà àjàrà rẹ, mo fẹ́ lo ilẹ̀ náà fún ọgbà ewébẹ̀ nítorí ó súnmọ́ tòsí ààfin mi. N óo fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju èyí lọ dípò rẹ̀, tabi tí ó bá sì wù ọ́, n óo san owó rẹ̀ fún ọ.” Naboti dáhùn pé, “Ọwọ́ àwọn baba ńlá mi ni mo ti jogún ọgbà àjàrà yìí; OLUWA má jẹ́ kí n rí ohun tí n óo fi gbé e fún ọ.” Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun. Jesebẹli, aya rẹ̀, wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí ọkàn rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì tóbẹ́ẹ̀ tí o kò fi jẹun?” Ahabu dá a lóhùn pé, “Mo sọ fún Naboti pé mo fẹ́ ra ọgbà àjàrà rẹ̀, tabi bí ó bá fẹ́, kí ó jẹ́ kí n fún un ni òmíràn dípò rẹ̀; ṣugbọn ó ní òun kò lè fún mi ní ọgbà àjàrà òun.” Jesebẹli, aya rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Họ́wù! Ṣebí ìwọ ni ọba Israẹli, àbí ìwọ kọ́? Dìde nílẹ̀ kí o jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn, n óo gba ọgbà àjàrà Naboti fún ọ.” Jesebẹli bá kọ ìwé ní orúkọ Ahabu, ó fi òǹtẹ̀ Ahabu tẹ̀ ẹ́, ó fi ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá ní ìlú tí Naboti ń gbé. Ohun tí ó kọ sinu ìwé náà ni pé, “Ẹ kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, ẹ pe àwọn eniyan jọ, ẹ sì fi Naboti jókòó ní ipò ọlá. Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.” Àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá tí wọn ń gbé ìlú náà ṣe bí Jesebẹli ti ní kí wọ́n ṣe ninu ìwé tí ó kọ ranṣẹ sí wọn. Wọ́n kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, wọ́n pe àwọn eniyan jọ, wọ́n sì fún Naboti ní ipò ọlá láàrin wọn. Àwọn eniyankeniyan meji tí wọ́n ya aṣa yìí jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n sì purọ́ mọ́ ọn lójú gbogbo eniyan pé ó bú Ọlọrun ati ọba. Wọ́n bá fà á jáde sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. Lẹ́yìn náà wọ́n ranṣẹ sí Jesebẹli pé àwọn ti sọ Naboti lókùúta pa. Bí Jesebẹli ti gbọ́ pé wọ́n ti sọ Naboti lókùúta pa, ó sọ fún Ahabu pé, “Gbéra nisinsinyii, kí o sì lọ gba ọgbà àjàrà tí Naboti kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí pé ó ti kú.” Lẹsẹkẹsẹ bí Ahabu ti gbọ́ pé Naboti ti kú, ó lọ sí ibi ọgbà àjàrà náà, ó sì gbà á. OLUWA bá sọ fún Elija wolii ará Tiṣibe pé, “Lọ bá Ahabu, ọba Israẹli, tí ń gbé Samaria; o óo bá a ninu ọgbà àjàrà Naboti, tí ó lọ gbà. Sọ pé, OLUWA ní kí o sọ fún un pé ṣé o ti pa ọkunrin yìí, o sì ti gba ọgbà àjàrà rẹ̀? Wí fún un pé, mo ní, ibi tí ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Naboti gan-an ni ajá yóo ti lá ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ náà.” Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó bi í pé, “O tún ti rí mi kọ́, ìwọ ọ̀tá mi?” Elija bá dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún ti rí ọ; nítorí pé o ti fa ara rẹ kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ burúkú níwájú OLUWA. OLUWA ní òun óo jẹ́ kí ibi bá ọ, òun óo pa ọ́ rẹ́, òun ó sì run gbogbo ọkunrin tí ń bẹ ninu ìdílé rẹ, ati ẹrú ati ọmọ. Ó ní bí òun ti ṣe ìdílé Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ti Baaṣa, ọmọ Ahija, bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣe ìdílé rẹ; nítorí o ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀, o sì ti mú òun OLUWA bínú. Ní ti Jesebẹli, OLUWA ní, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀ láàrin ìlú Jesireeli. Ẹni tí ó bá kú sí ààrin ìlú ninu ìdílé ìwọ Ahabu, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì kú sinu pápá, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.” (Kò sí ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ burúkú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Ahabu, tí Jesebẹli aya rẹ̀, ń tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láti ṣe iṣẹ́ burúkú. Gbogbo ọ̀nà ìríra tí àwọn ará Amori ń gbà bọ oriṣa ni Ahabu pàápàá ń gbà bọ oriṣa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni lílé sì ni OLUWA lé àwọn ará Amori jáde kúrò ní ilẹ̀ Kenaani fún àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀.) Nígbà tí Elija parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ahabu fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó bọ́ wọn kúrò, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Ó gbààwẹ̀, orí aṣọ ọ̀fọ̀ ni ó sì ń sùn; ó sì ń káàkiri pẹlu ìdoríkodò ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. OLUWA tún sọ fún Elija pé, “Ǹjẹ́ o ṣe akiyesi bí Ahabu ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí pé ó ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ báyìí, n kò ní jẹ́ kí ibi tí mo wí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ kí n tó jẹ́ kí ibi ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ̀.”

I. A. Ọba 21:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Naboti ará Jesreeli sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jesreeli, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Ahabu ọba Samaria. Ahabu sì wí fún Naboti pé, “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi; Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀; tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ.” Ṣùgbọ́n Naboti wí fún Ahabu pé, “OLúWA má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn baba mi fún ọ.” Ahabu sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Naboti ará Jesreeli sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn baba mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun. Jesebeli aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, Èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún Naboti ará Jesreeli pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, Èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ” Jesebeli aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Israẹli? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Naboti ará Jesreeli.” Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Ahabu, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Naboti pẹ̀lú rẹ̀. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé: “Ẹ kéde àwẹ̀, kí ẹ sì fi Naboti sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú síwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí sí i wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú Naboti sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwé tí Jesebeli kọ ránṣẹ́ sí wọn. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, wọ́n sì fi Naboti sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí lòdì sí Naboti níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Naboti ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jesebeli wí pé: “A ti sọ Naboti ní òkúta, ó sì kú.” Bí Jesebeli sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Naboti ní Òkúta pa, ó sì wí fún Ahabu pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Naboti, ará Jesreeli, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láààyè mọ́, ó ti kú.” Nígbà tí Ahabu sì gbọ́ pé Naboti ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà Naboti. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé; “Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀. Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ” Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú OLúWA. ‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Ahabu gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Israẹli. Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jeroboamu, ọmọ Nebati, àti bí ilé Baaṣa, ọmọ Ahijah, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Israẹli ṣẹ̀.’ “Àti ní ti Jesebeli pẹ̀lú OLúWA wí pé: ‘Àwọn ajá yóò jẹ Jesebeli nínú yàrá Jesreeli.’ “Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Ahabu tí ó kú ní ìlú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ àwọn ẹni tí ó kú ní igbó.” (Kò sí ẹnìkan bí Ahabu tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe búburú níwájú OLúWA, ẹni tí Jesebeli aya rẹ̀ ń tì. Ó sì ṣe ohun ìríra gidigidi ní tí tọ òrìṣà lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwọn ará Amori ti ṣe, tí OLúWA lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli.) Nígbà tí Ahabu sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sí ara rẹ̀, ó sì gbààwẹ̀. Ó sì dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ń lọ jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé: “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀.”