I. A. Ọba 2:13-27

I. A. Ọba 2:13-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni. On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi: On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá. Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi. O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya. Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ. Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀. On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ. On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya. Solomoni ọba si dahùn, o si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbere Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, kuku bere ijọba fun u pẹlu; nitori ẹgbọ́n mi ni iṣe; fun on pãpa, ati fun Abiatari, alufa, ati fun Joabu, ọmọ Seruiah. Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀. Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah. Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú. Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ. Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo.

I. A. Ọba 2:13-27 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan, Adonija ọmọ Hagiti, lọ sí ọ̀dọ̀ Batiṣeba, ìyá Solomoni. Batiṣeba bá bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni o?” Adonija dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, kinní kan ni mo fẹ́ bá ọ sọ.” Batiṣeba bi í pé, “Kí ni?” Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA. Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.” Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?” Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.” Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.” Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀. Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.” Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú. Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.” Ọba bá bi ìyá rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún un ní Abiṣagi nìkan? Ò bá kúkú ní kí n dìde fún un lórí ìtẹ́ tí mo wà yìí. Ṣebí òun ni ẹ̀gbọ́n mi, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni Abiatari alufaa ati Joabu ọmọ Seruaya wà.” Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.” Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.” Solomoni bá yọ Abiatari kúrò ninu iṣẹ́ alufaa OLUWA tí ó ń ṣe, ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ ní Ṣilo ṣẹ, nípa Eli alufaa ati arọmọdọmọ rẹ̀.

I. A. Ọba 2:13-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.” Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.” Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ OLúWA wá. Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ó wí pé, “O lè wí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (Òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.” Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.” Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.” Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!” Nígbà náà ni Solomoni ọba fi OLúWA búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé OLúWA wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!” Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú. Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà OLúWA, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ.