I. A. Ọba 2:1-9

I. A. Ọba 2:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌJỌ Dafidi si sunmọ etile ti yio kú: o si paṣẹ fun Solomoni, ọmọ rẹ̀ pe: Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin. Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si. Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli. Iwọ si mọ̀ pẹlu, ohun ti Joabu, ọmọ Seruiah, ṣe si mi, ati ohun ti o ṣe si balogun meji ninu awọn ọgagun Israeli, si Abneri, ọmọ Neri, ati si Amasa, ọmọ Jeteri, o si pa wọn, o si ta ẹ̀jẹ ogun silẹ li alafia, o si fi ẹ̀jẹ ogun si ara àmure rẹ̀ ti mbẹ li ẹ̀gbẹ rẹ̀, ati si ara salubata rẹ̀ ti mbẹ li ẹsẹ rẹ̀. Nitorina, ki o ṣe gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ, ki o má si jẹ ki ewu ori rẹ̀ ki o sọkalẹ lọ si isa-okú li alafia. Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ. Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ. Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú.

I. A. Ọba 2:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Dafidi jáde láyé, ó pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fún un pé, “Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin. Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ. Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú. “Siwaju sí i, ranti ohun tí Joabu ọmọ Seruaya ṣe sí mi, tí ó pa àwọn ọ̀gágun Israẹli meji: Abineri ọmọ Neri ati Amasa ọmọ Jeteri. Ranti pé ní àkókò tí kò sí ogun ni ó pa wọ́n; tí ó fi gbẹ̀san ikú ẹni tí wọ́n pa ní àkókò ogun. Pípa tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀ wọnyi, ọrùn mi ni ó pa wọ́n sí, ẹrù ẹ̀bi wọn sì wà lórí mi. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú. “Ṣugbọn òtítọ́ inú ni kí o máa fi bá àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi lò. Jẹ́ kí wọ́n wà lára àwọn tí yóo máa bá ọ jẹun pọ̀, nítorí pé òótọ́ inú ni wọ́n fi wá pàdé mi ní àkókò tí mò ń sá lọ fún Absalomu, arakunrin rẹ. “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ láìjìyà. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.”

I. A. Ọba 2:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀. Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, kí o sì wòye ohun tí OLúWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, kí OLúWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’ “Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí Balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà. “Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ. “Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi OLúWA búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”