I. A. Ọba 2:1-46

I. A. Ọba 2:1-46 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌJỌ Dafidi si sunmọ etile ti yio kú: o si paṣẹ fun Solomoni, ọmọ rẹ̀ pe: Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin. Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si. Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli. Iwọ si mọ̀ pẹlu, ohun ti Joabu, ọmọ Seruiah, ṣe si mi, ati ohun ti o ṣe si balogun meji ninu awọn ọgagun Israeli, si Abneri, ọmọ Neri, ati si Amasa, ọmọ Jeteri, o si pa wọn, o si ta ẹ̀jẹ ogun silẹ li alafia, o si fi ẹ̀jẹ ogun si ara àmure rẹ̀ ti mbẹ li ẹ̀gbẹ rẹ̀, ati si ara salubata rẹ̀ ti mbẹ li ẹsẹ rẹ̀. Nitorina, ki o ṣe gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ, ki o má si jẹ ki ewu ori rẹ̀ ki o sọkalẹ lọ si isa-okú li alafia. Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ. Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ. Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú. Dafidi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni ilu Dafidi. Ọjọ ti Dafidi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun: ni Hebroni o jọba li ọdun meje, ni Jerusalemu o si jọba li ọdun mẹtalelọgbọn. Solomoni si joko lori itẹ Dafidi baba rẹ̀; a si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ gidigidi. Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni. On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi: On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá. Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi. O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya. Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ. Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀. On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ. On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya. Solomoni ọba si dahùn, o si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbere Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, kuku bere ijọba fun u pẹlu; nitori ẹgbọ́n mi ni iṣe; fun on pãpa, ati fun Abiatari, alufa, ati fun Joabu, ọmọ Seruiah. Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀. Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah. Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú. Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ. Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo. Ihin si de ọdọ Joabu: nitori Joabu ti tọ̀ Adonijah lẹhin, ṣugbọn kò tọ̀ Absalomu lẹhin: Joabu si sá sinu agọ Oluwa, o si di iwo pẹpẹ mu. A si sọ fun Solomoni ọba pe, Joabu ti sá sinu agọ Oluwa; si wò o, o sunmọ pẹpẹ, Solomoni si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, pe, Lọ, ki o si kọlù u. Benaiah si wá sinu agọ Oluwa, o si wi fun u pe, Bayi li ọba wi, pe, Jade wá. On si wipe, Bẹ̃kọ̀; ṣugbọn nihinyi li emi o kú. Benaiah si mu èsi fun ọba wá pe, Bayi ni Joabu wi, bayi ni o si dá mi lohùn. Ọba si wi fun u pe, Ṣe gẹgẹ bi o ti wi ki o si kọlù u, ki o si sin i, ki iwọ ki o le mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lọdọ mi ati kuro lọdọ ile baba mi, ti Joabu ti ta silẹ. Oluwa yio si yi ẹ̀jẹ rẹ̀ pada sori rẹ̀, nitoriti o kọlù ọkunrin meji ti o ṣe olododo, ti o sàn jù on tikararẹ̀ lọ, o si fi idà pa wọn. Dafidi baba mi kò si mọ̀, ani, Abneri, ọmọ Neri, olori ogun, ati Amasa, ọmọ Jeteri, olori ogun Juda. Ẹ̀jẹ wọn yio si pada sori Joabu, ati sori iru-ọmọ rẹ̀ lailai: ṣugbọn si Dafidi ati si iru-ọmọ rẹ̀, ati si ile rẹ̀, ati si itẹ́ rẹ̀, alafia yio wà lati ọdọ Oluwa wá, Benaiah, ọmọ Jehoiada, si goke, o si kọlù u, ó si pa a: a si sin i ni ile rẹ̀ li aginju. Ọba si fi Benaiah, ọmọ Jehoiada, jẹ olori-ogun ni ipò rẹ̀, ati Sadoku alufa ni ọba fi si ipò Abiatari. Ọba si ranṣẹ, o si pe Ṣimei, o si wi fun u pe, Kọ́ ile fun ara rẹ ni Jerusalemu, ki o si ma gbe ibẹ̀, ki o má si ṣe jade lati ibẹ lọ si ibikibi. Yio si ṣe li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si kọja odò Kidroni, ki iwọ mọ̀ dajudaju pe, Kikú ni iwọ o kú; ẹ̀jẹ rẹ yio wà lori ara rẹ. Ṣimei si wi fun ọba pe, Ọrọ na dara, gẹgẹ bi oluwa mi ọba ti wi, bẹ̃ gẹgẹ ni iranṣẹ rẹ yio ṣe. Ṣimei si gbe Jerusalemu li ọjọ pupọ. O si ṣe lẹhin ọdun mẹta, awọn ọmọ-ọdọ Ṣimei meji si lọ sọdọ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati. Nwọn si rò fun Ṣimei pe, Wo o, awọn ọmọ-ọdọ rẹ mbẹ ni Gati. Ṣimei si dide, o si di kẹtẹkẹtẹ ni gari, o si lọ, o si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ bọ̀ lati Gati. A si rò fun Solomoni pe, Ṣimei ti lọ lati Jerusalemu si Gati, o si pada bọ̀. Ọba si ranṣẹ, o si pè Ṣimei, o si wi fun u pe, emi kò ti mu ọ fi Oluwa bura, emi kò si ti fi ọ ṣe ẹlẹri, pe, Li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si rìn jade lọ nibikibi, ki iwọ ki o mọ̀ dajudaju pe, kikú ni iwọ o kú? iwọ si wi fun mi pe, Ọrọ na ti mo gbọ́, o dara. Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ? Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ. A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai. Ọba si paṣẹ fun Benaiah ọmọ Jehoiada, o si jade lọ, o si kọlù u, o si kú. A si fi idi ijọba mulẹ li ọwọ́ Solomoni.

I. A. Ọba 2:1-46 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Dafidi jáde láyé, ó pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fún un pé, “Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin. Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ. Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú. “Siwaju sí i, ranti ohun tí Joabu ọmọ Seruaya ṣe sí mi, tí ó pa àwọn ọ̀gágun Israẹli meji: Abineri ọmọ Neri ati Amasa ọmọ Jeteri. Ranti pé ní àkókò tí kò sí ogun ni ó pa wọ́n; tí ó fi gbẹ̀san ikú ẹni tí wọ́n pa ní àkókò ogun. Pípa tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀ wọnyi, ọrùn mi ni ó pa wọ́n sí, ẹrù ẹ̀bi wọn sì wà lórí mi. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú. “Ṣugbọn òtítọ́ inú ni kí o máa fi bá àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi lò. Jẹ́ kí wọ́n wà lára àwọn tí yóo máa bá ọ jẹun pọ̀, nítorí pé òótọ́ inú ni wọ́n fi wá pàdé mi ní àkókò tí mò ń sá lọ fún Absalomu, arakunrin rẹ. “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ láìjìyà. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.” Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Dafidi, ọba kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi. Ogoji ọdún ni ó fi jọba Israẹli. Ó ṣe ọdún meje lórí oyè ní Heburoni, ó sì ṣe ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu. Solomoni gorí oyè lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin. Ní ọjọ́ kan, Adonija ọmọ Hagiti, lọ sí ọ̀dọ̀ Batiṣeba, ìyá Solomoni. Batiṣeba bá bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni o?” Adonija dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, kinní kan ni mo fẹ́ bá ọ sọ.” Batiṣeba bi í pé, “Kí ni?” Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA. Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.” Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?” Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.” Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.” Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀. Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.” Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú. Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.” Ọba bá bi ìyá rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún un ní Abiṣagi nìkan? Ò bá kúkú ní kí n dìde fún un lórí ìtẹ́ tí mo wà yìí. Ṣebí òun ni ẹ̀gbọ́n mi, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni Abiatari alufaa ati Joabu ọmọ Seruaya wà.” Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.” Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.” Solomoni bá yọ Abiatari kúrò ninu iṣẹ́ alufaa OLUWA tí ó ń ṣe, ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ ní Ṣilo ṣẹ, nípa Eli alufaa ati arọmọdọmọ rẹ̀. Nígbà tí Joabu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, nítorí pé lẹ́yìn Adonija ni ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́yìn Absalomu. Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Joabu ti sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ati pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, Solomoni rán Bẹnaya kí ó lọ pa á. Bẹnaya bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó wí fún Joabu pé, “Ọba pàṣẹ pé kí o jáde.” Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn, ó ní, “Rárá, níhìn-ín ni n óo kú sí.” Bẹnaya bá pada lọ sọ ohun tí Joabu wí fún ọba. Ọba dá a lóhùn pé, “Ṣe bí Joabu ti ní kí o ṣe. Pa á, kí o sì sin ín. Nígbà náà ni ọrùn èmi, ati arọmọdọmọ Dafidi yóo tó mọ́ kúrò ninu ohun tí Joabu ṣe nígbà tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀. OLUWA yóo jẹ Joabu níyà fún àwọn eniyan tí ó pa láìjẹ́ pé Dafidi baba mí mọ ohunkohun nípa rẹ̀. Ó pa Abineri, ọmọ Neri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Israẹli ati Amasa, ọmọ Jeteri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn mejeeji tí ó pa láìṣẹ̀ yìí ṣe olóòótọ́ ju òun pàápàá lọ. Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa yóo wà lórí rẹ̀ ati lórí àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ títí lae, ṣugbọn OLUWA yóo fún Dafidi ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ ati ilé rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀ ní alaafia títí lae.” Bẹnaya ọmọ Jehoiada bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó pa Joabu, wọn sì sin ín sinu ilé rẹ̀ ninu aṣálẹ̀. Ọba fi Bẹnaya jẹ balogun rẹ̀ dípò Joabu, ó sì fi Sadoku jẹ alufaa dípò Abiatari. Lẹ́yìn náà, ọba ranṣẹ pe Ṣimei, ó wí fún un pé, “Kọ́ ilé kan sí Jerusalẹmu níhìn-ín kí o sì máa gbé ibẹ̀. O kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ibìkankan. Ọjọ́ tí o bá jáde kọjá odò Kidironi, pípa ni n óo pa ọ́, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóo sì wà lórí ara rẹ.” Ṣimei dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ ni ó dára, oluwa mi, bí o ti wí ni èmi iranṣẹ rẹ yóo sì ṣe.” Ṣimei sì wà ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́. Lẹ́yìn ọdún mẹta, àwọn ẹrú Ṣimei meji kan sá lọ sí ọ̀dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maaka, ọba ìlú Gati. Nígbà tí Ṣimei gbọ́ pé àwọn ẹrú rẹ̀ yìí wà ní Gati, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kan ní gàárì, ó sì tọ Akiṣi ọba lọ sí ìlú Gati láti lọ wá àwọn ẹrú rẹ̀. Ó rí wọn, ó sì mú àwọn mejeeji pada wá sí ilé. Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Ṣimei ti kúrò ní Jerusalẹmu, ó ti lọ sí Gati, ó sì ti pada, ó ranṣẹ pè é, ó bi í pé, “Ṣebí o búra fún mi ní orúkọ OLUWA pé o kò ní jáde kúrò ní Jerusalẹmu? Mo sì kìlọ̀ fún ọ pé, ní ọjọ́ tí o bá jáde, pípa ni n óo pa ọ́. O gbà bẹ́ẹ̀, o sì ṣèlérí fún mi pé o óo pa òfin náà mọ́. Kí ló dé tí o kò mú ìlérí rẹ fún OLUWA ṣẹ, tí o sì rú òfin mi?” Dájúdájú o mọ gbogbo ibi tí o ṣe sí Dafidi, baba mi; OLUWA yóo jẹ ọ́ níyà ohun tí o ṣe. Ṣugbọn OLUWA yóo bukun mi, yóo sì fi ẹsẹ̀ ìjọba Dafidi múlẹ̀ títí lae. Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, pé kí ó lọ pa Ṣimei; Bẹnaya bá jáde lọ, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà ni gbogbo ìjọba Solomoni ọba wá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

I. A. Ọba 2:1-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀. Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, kí o sì wòye ohun tí OLúWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, kí OLúWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’ “Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí Balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà. “Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ. “Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi OLúWA búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.” Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Dafidi ti jẹ ọba lórí Israẹli ní ogójì ọdún (40), ọdún méje (7) ni Hebroni àti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ní Jerusalẹmu. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi. Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.” Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.” Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ OLúWA wá. Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ó wí pé, “O lè wí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (Òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.” Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.” Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.” Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!” Nígbà náà ni Solomoni ọba fi OLúWA búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé OLúWA wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!” Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú. Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà OLúWA, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ. Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ OLúWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ OLúWA àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.” Benaiah sì wọ inú àgọ́ OLúWA, ó sì wí fún Joabu pé, “ọba sọ wí pé, Jáde wá.” Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn-ín.” Benaiah sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Joabu ṣe dá mi lóhùn.” Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀. OLúWA yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ. Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà OLúWA wà títí láé.” Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari. Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn. Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá Àfonífojì Kidironi, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.” Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.” Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati. Nígbà tí a sì sọ fún Solomoni pé Ṣimei ti lọ láti Jerusalẹmu sí Gati, ó sì ti padà, Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti OLúWA, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’ Èéṣe, nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra OLúWA mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?” Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, OLúWA yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ. Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú OLúWA títí láéláé.” Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣimei, ó sì pa á. Ìjọba náà sì wá fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ Solomoni.