I. A. Ọba 19:14-21

I. A. Ọba 19:14-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria. Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ. Yio si ṣe, ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Hasaeli ni Jehu yio pa, ati ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Jehu ni Eliṣa yio pa. Ṣugbọn emi ti kù ẹ̃dẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israeli, gbogbo ẽkun ti kò tii kunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kò iti fi ẹnu kò o li ẹnu. Bẹ̃ni o pada kuro nibẹ, o si ri Eliṣa, ọmọ Ṣafati o nfi àjaga malu mejila tulẹ niwaju rẹ̀, ati on na pẹlu ikejila: Elijah si kọja tọ̀ ọ lọ, o si da agbáda rẹ̀ bò o. O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ? O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u.

I. A. Ọba 19:14-21 Yoruba Bible (YCE)

Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Pada lọ sinu aṣálẹ̀ ẹ̀bá Damasku. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, fi àmì òróró yan Hasaeli ní ọba Siria. Yan Jehu, ọmọ Nimṣi, ní ọba Israẹli, kí o sì yan Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ará Abeli Mehola, ní wolii dípò ara rẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hasaeli, Jehu ni yóo pa á, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jehu, Eliṣa ni yóo pa á. Sibẹsibẹ n óo dá ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan sí, ní ilẹ̀ Israẹli: àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí mi, tí wọn kò tíì kúnlẹ̀ fún oriṣa Baali, tabi kí wọ́n fi ẹnu wọn kò ó lẹ́nu.” Nígbà tí ó yá, Elija bá kúrò níbẹ̀, bí ó ti ń lọ ó bá Eliṣa ọmọ Ṣafati níbi tí ó tí ń fi àjàgà mààlúù mejila kọ ilẹ̀. Àjàgà mààlúù mọkanla wà níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń kọ ilẹ̀ lọ. Òun alára wà pẹlu àjàgà mààlúù tí ó kẹ́yìn, ó ń fi í kọ ilẹ̀. Elija kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó gbé e wọ Eliṣa. Eliṣa fi àjàgà mààlúù rẹ̀ sílẹ̀, ó sáré tẹ̀lé Elija, o wí fún un pé, “Jẹ́ kí n lọ dágbére fún baba ati ìyá mi, kí n fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, kí n tó máa tẹ̀lé ọ.” Elija dá a lóhùn pé, “Pada lọ, àbí, kí ni mo ṣe fún ọ?” Eliṣa bá pada lẹ́yìn rẹ̀ sí ibi tí àwọn akọ mààlúù rẹ̀ wà, ó pa wọ́n. Ó fi igi tí ó fi ṣe àjàgà wọn ṣe igi ìdáná, ó bá se ẹran wọn. Ó pín ẹran náà fún àwọn eniyan, wọ́n sì jẹ ẹ́. Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Elija, ó ń tẹ̀lé e, ó sì ń ṣe iranṣẹ fún un.

I. A. Ọba 19:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.” OLúWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu. Tún fi òróró yan Jehu ọmọ Nimṣi ní ọba lórí Israẹli, àti kí o fi òróró yan Eliṣa ọmọ Ṣafati, ará Abeli-Mehola ní wòlíì ní ipò rẹ. Jehu yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hasaeli, Eliṣa yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jehu. Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó. Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Elijah sì dáhùn wí pé, “Padà sẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?” Eliṣa sì fi í sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Elijah lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.