I. A. Ọba 16:8-20

I. A. Ọba 16:8-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li ọdun kẹrindilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Tirsa li ọdun meji. Ati iranṣẹ rẹ̀ Simri, olori idaji kẹkẹ́ rẹ̀, dìtẹ rẹ̀, nigbati o ti wà ni Tirsa, o si mu amupara ni ile Arsa, iriju ile rẹ̀ ni Tirsa. Simri si wọle o si kọlù u, o si pa a, li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, o si jọba ni ipò rẹ̀. O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀. Bayi ni Simri pa gbogbo ile Baaṣa run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ si Baaṣa nipa ọwọ́ Jehu woli, Nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ Baaṣa, ati Ela, ọmọ rẹ̀, nipa eyiti nwọn ṣẹ̀, ati nipa eyiti nwọn mu Israeli ṣẹ̀, ni fifi ohun-asán wọn wọnnì mu ki Oluwa, Ọlọrun Israeli binu. Ati iyokù iṣe Ela, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Simri jọba ijọ meje ni Tirsa. Awọn enia si do tì Gibbetoni, ti awọn ara Filistia. Awọn enia ti o dotì gbọ́ wipe, Simri ditẹ̀ o si ti pa ọba pẹlu: nitorina gbogbo Israeli fi Omri, olori ogun, jẹ ọba lori Israeli li ọjọ na ni ibudo. Omri si goke lati Gibbetoni lọ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, nwọn si do tì Tirsa. O si ṣe, nigbati Simri mọ̀ pe a gba ilu, o wọ inu ãfin ile ọba lọ, o si tẹ iná bọ ile ọba lori ara rẹ̀, o si kú. Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀. Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

I. A. Ọba 16:8-20 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kẹrindinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli; ó sì jọba ní Tirisa fún ọdún meji. Simiri, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀, alabojuto ìdajì àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ní ọjọ́ kan, níbi tí ó ti ń mu ọtí àmupara ní ilé Arisa, alabojuto ààfin, ní Tirisa, ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa ọba Juda gorí oyè, Simiri bá wọlé, ó fi idà ṣá Ela pa, ó bá fi ara rẹ̀ jọba dípò Ela. Bí Simiri ti gorí oyè, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba ni ó pa gbogbo àwọn ìdílé Baaṣa patapata. Gbogbo àwọn ìbátan ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọkunrin ni ó pa láìdá ẹnikẹ́ni sí. Báyìí ni Simiri ṣe pa gbogbo ìdílé Baaṣa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu wolii Jehu, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa ati Ela ọmọ rẹ̀ dá ati èyí tí wọ́n mú kí Israẹli dá, tí wọ́n mú kí OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ela ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, Simiri gorí oyè ní Tirisa, ó sì jọba Israẹli fún ọjọ́ meje. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ogun Israẹli gbógun ti ìlú Gibetoni ní ilẹ̀ Filistia. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé, Simiri ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ati pé ó ti pa á, lẹsẹkẹsẹ ni gbogbo Israẹli fi Omiri olórí ogun, jọba Israẹli ninu àgọ́ wọn ní ọjọ́ náà. Omiri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá kúrò ní ìlú Gibetoni, wọ́n lọ dó ti ìlú Tirisa. Nígbà tí Simiri rí i pé ọwọ́ ti tẹ ìlú náà, ó lọ sí ibi ààbò tí ó wà ninu ààfin, ó tiná bọ ààfin, ó sì kú sinu iná; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, tí ó tọ ọ̀nà tí Jeroboamu tọ̀, ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá: tí ó mú kí àwọn ọmọ Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

I. A. Ọba 16:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, Ela ọmọ Baaṣa bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba ní Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Tirsa ní ọdún méjì. Simri, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Ela sì wà ní Tirsa nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Arsa, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tirsa. Simri sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Asa, ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Baaṣa pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni Simri pa gbogbo ilé Baaṣa run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó sọ sí Baaṣa nípa ọwọ́ Jehu wòlíì: nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa àti Ela ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Israẹli ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú OLúWA Ọlọ́run Israẹli bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn. Ìyókù ìṣe Ela àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, ni Simri jẹ ọba ọjọ́ méje ní Tirsa. Àwọn ọmọ-ogun sì dó ti Gibetoni, ìlú àwọn ará Filistini. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí ó dó tì gbọ́ wí pé Simri ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Omri, olórí ogun, bí ọba lórí Israẹli ní ọjọ́ náà ní ibùdó. Nígbà náà ni Omri àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gibetoni, wọ́n sì dó ti Tirsa. Nígbà tí Simri sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú OLúWA àti ní rírìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀. Ní ti ìyókù ìṣe Simri, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli?