I. A. Ọba 13:1-2
I. A. Ọba 13:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
SI kiyesi i, enia Ọlọrun kan lati Juda wá si Beteli nipa ọ̀rọ Oluwa: Jeroboamu duro lẹba pẹpẹ lati fi turari jona. O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ.
I. A. Ọba 13:1-2 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA pàṣẹ fún wolii kan, ará Juda, pé kí ó lọ sí Bẹtẹli; nígbà tí ó débẹ̀ ó bá Jeroboamu tí ó dúró níwájú pẹpẹ láti sun turari. Wolii náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ sí pẹpẹ náà, ó ní, “Ìwọ pẹpẹ yìí, ìwọ pẹpẹ yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ó ní, ‘Wò ó! A óo bí ọmọ kan ninu ìdílé Dafidi, orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́ Josaya. Lórí ìwọ pẹpẹ yìí ni yóo ti fi àwọn alufaa oriṣa tí ń sun turari lórí rẹ rúbọ. A óo sì máa sun egungun eniyan lórí rẹ.’ ”
I. A. Ọba 13:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ OLúWA, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ OLúWA wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni OLúWA wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ”