I. A. Ọba 11:2-4
I. A. Ọba 11:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn orilẹ-ède ti Oluwa wi fun awọn ọmọ-Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ wọle tọ̀ wọn, bẹ̃ni awọn kò gbọdọ wọle tọ̀ nyin: nitõtọ nwọn o yi nyin li ọkàn pada si oriṣa wọn: Solomoni fà mọ awọn wọnyi ni ifẹ. O si ni ẽdẹgbẹrin obinrin, awọn ọmọ ọba, ati ọ̃dunrun alè, awọn aya rẹ̀ si yi i li ọkàn pada. O si ṣe, nigbati Solomoni di arugbo, awọn obinrin rẹ̀ yi i li ọkàn pada si ọlọrun miran: ọkàn rẹ̀ kò si ṣe dede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rẹ̀.
I. A. Ọba 11:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Solomoni ọba fẹ́ wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli tẹ́lẹ̀, pé wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọmọ fún wọn; kí àwọn orílẹ̀-èdè náà má baà mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli ṣí sọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn. Ẹẹdẹgbẹrin (700) ni àwọn obinrin ati ọmọ ọba tí Solomoni gbé níyàwó, ó sì tún ní ọọdunrun (300) obinrin mìíràn. Àwọn obinrin náà sì mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí Solomoni di àgbàlagbà, àwọn iyawo rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ó ń bọ àwọn oriṣa àjèjì, kò sì ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ mọ́, bíi Dafidi, baba rẹ̀.
I. A. Ọba 11:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí OLúWA ti wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀ Solomoni fàmọ́ wọn ní ìfẹ́. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà. Bí Solomoni sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.