I. Kor 9:13-14
I. Kor 9:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ? Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere.
I. Kor 9:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kò mọ̀ pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu Tẹmpili a máa jẹ lára ẹbọ, ati pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ a máa pín ninu nǹkan ìrúbọ tí ó wà lórí pẹpẹ? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere.
I. Kor 9:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìhìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìhìnrere.