I. Kor 3:6-21
I. Kor 3:6-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá. Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá. Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirẹ̀ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ̀. Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin. Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi. Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, akekù koriko le ori ipilẹ yi; Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe. Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ̀ ba duro, on ó gbà ère. Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja. Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin? Bi ẹnikan bá ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, on ni Ọlọrun yio parun; nitoripe mimọ́ ni tẹmpili Ọlọrun, eyiti ẹnyin jẹ. Ki ẹnikẹni máṣe tàn ara rẹ̀ jẹ. Bi ẹnikẹni ninu nyin laiye yi ba rò pe on gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, ki o le ba gbọ́n. Nitori ọgbọ́n aiye yi wèrè ni lọdọ Ọlọrun. Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹniti o mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke wọn. A si tún kọ ọ pe, Oluwa mọ̀ ero ironu awọn ọlọgbọ́n pe, asan ni nwọn. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe ṣogo ninu enia. Nitori tinyin li ohun gbogbo
I. Kor 3:6-21 Yoruba Bible (YCE)
Èmi gbin irúgbìn, Apolo bomi rin ohun tí mo gbìn, ṣugbọn Ọlọrun ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn dàgbà. Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà. Ọ̀kan ni ẹni tí ó ń gbin irúgbìn ati ẹni tí ó ń bomi rin ín. Nígbà tí ó bá yá, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóo gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Nítorí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni wá lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ẹ̀yin ni ọgbà Ọlọrun. Tẹmpili Ọlọrun sì ni yín. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀lé tí ó mòye, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi, ẹlòmíràn wá ń kọ́lé lé e lórí. Ṣugbọn kí olukuluku ṣọ́ra pẹlu irú ohun tí ó ń mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. Nítorí kò sí ìpìlẹ̀ kan tí ẹnikẹ́ni tún lè fi lélẹ̀ mọ́, yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọrun ti fi lélẹ̀, tíí ṣe Jesu Kristi. Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá mọ wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta iyebíye, tabi igi, tabi koríko tabi fùlùfúlù lé orí ìpìlẹ̀ yìí, iṣẹ́ olukuluku yóo farahàn kedere ní ọjọ́ ìdájọ́, nítorí iná ni yóo fi í hàn. Iná ni a óo fi dán iṣẹ́ olukuluku wò. Bí ohun tí ẹnikẹ́ni bá kọ́ lé orí ìpìlẹ̀ yìí kò bá jóná, olúwarẹ̀ yóo gba èrè. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, olúwarẹ̀ yóo pòfo, ṣugbọn òun alára yóo lá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹni tí a fà yọ ninu iná ni. Àbí ẹ kó mọ̀ pé Tẹmpili Ọlọrun ni yín ni, ati pé Ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú yín? Bí ẹnikẹ́ni bá ba Tẹmpili Ọlọrun jẹ́. Ọlọrun yóo pa òun náà run. Nítorí mímọ́ ni Tẹmpili Ọlọrun, ẹ̀yin náà sì ni Tẹmpili Ọlọrun. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Bí ẹnìkan ninu yín bá rò pé òun gbọ́n ọgbọ́n ti ayé yìí, kí ó ka ara rẹ̀ sí òmùgọ̀ kí ó lè gbọ́n. Nítorí agọ̀ ni ọgbọ́n ayé yìí lójú Ọlọrun. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn.” Níbòmíràn, ó tún wí pé, “Oluwa mọ̀ pé asán ni èrò-inú àwọn ọlọ́gbọ́n.” Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tìtorí eniyan gbéraga, nítorí tiyín ni ohun gbogbo
I. Kor 3:6-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa. Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá. Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹmpili Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹmpili Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yin jẹ́. Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo.