I. Kor 1:13-17
I. Kor 1:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si? Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe emi kò baptisi ẹnikẹni ninu nyin, bikoṣe Krispu ati Gaiu; Ki ẹnikẹni ki o máṣe wipe mo ti mbaptisi li orukọ emi tikarami. Mo si baptisi awọn ara ile Stefana pẹlu: lẹhin eyi emi kò mọ̀ bi mo ba baptisi ẹlomiran pẹlu. Nitori Kristi kò rán mi lọ ibaptisi, bikoṣe lati wãsu ihinrere: kì iṣe nipa ọgbọ́n ọ̀rọ, ki a máṣe sọ agbelebu Kristi di alailagbara.
I. Kor 1:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Ṣé Kristi náà ni ó wá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ báyìí? Ṣé èmi Paulu ni wọ́n kàn mọ́ agbelebu fun yín? Àbí ní orúkọ Paulu ni wọ́n ṣe ìrìbọmi fun yín? Mo dúpẹ́ pé n kò ṣe ìrìbọmi fún ẹnikẹ́ni ninu yín, àfi Kirisipu ati Gaiyu. Kí ẹnikẹ́ni má baà wí pé orúkọ mi ni wọ́n fi ṣe ìrìbọmi fún òun. Mo tún ranti! Mo ṣe ìrìbọmi fún ìdílé Stefana. N kò tún ranti ẹlòmíràn tí mo ṣe ìrìbọmi fún mọ́. Nítorí pé Kristi kò fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrìbọmi rán mi, iṣẹ́ iwaasu ìyìn rere ni ó fi rán mi, kì í sìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, kí agbelebu Kristi má baà di òfo.
I. Kor 1:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí? Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiu. Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi. (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi). Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìhìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.