I. Kro 9:1-3
I. Kro 9:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Awọn ti o tetekọ gbe ilẹ ini wọn, ati ilu wọn li awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu. Ni Jerusalemu ni, ninu awọn ọmọ Juda, ati ninu awọn ọmọ Benjamini, ati ninu awọn ọmọ Efraimu, ati Manasse ngbe
I. Kro 9:1-3 Yoruba Bible (YCE)
A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli. A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili. Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí
I. Kro 9:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn. Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn Ìránṣẹ́ ilé OLúWA. Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́