I. Kro 29:1-9
I. Kro 29:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI ọba si wi fun gbogbo ijọ enia pe, Solomoni ọmọ mi, on nikan ti Ọlọrun ti yàn, jẹ ọmọde o si rọ̀, iṣẹ na si tobi: nitori ti ãfin na kì iṣe fun enia, ṣugbọn fun Ọlọrun Oluwa. Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tẹ̀ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọ̀pọlọpọ. Pẹlupẹlu, nitori ni didùn inu mi si ile Ọlọrun mi, mo fi ohun ini mi, eyinì ni wura ati fadakà, fun ile Ọlọrun mi, jù gbogbo eyi ti mo ti pèse silẹ fun ile mimọ́ na, Ẹgbẹ̃dogun talenti wura, ti wura Ofiri, ati ẹ̃dẹgbarin talenti fadakà didara, lati fi bo ogiri ile na: Wura fun ohun èlo wura, ati fadakà fun ohun èlo fadakà, ati fun oniruru iṣẹ nipa ọwọ awọn ọlọnà. Tani si nfẹ loni lati yà ara rẹ̀ si mimọ fun Oluwa? Nigbana ni awọn olori awọn baba ati awọn ijoye ẹ̀ya Israeli, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun, pẹlu awọn ijoye iṣẹ ọba fi tinutinu ṣe iranlọwọ, Nwọn si fi fun iṣẹ ile Ọlọrun, ti wura ẹgbẹ̃dọgbọ̀n talenti ati ẹgbãrun dramu, ati ti fadakà ẹgbãrun talenti, ati ti bàba ẹgbãsan talenti, ati ọkẹ marun talenti irin. Ati awọn ti a ri okuta iyebiye lọdọ wọn fi i sinu iṣura ile Oluwa, nipa ọwọ Jehieli ara Gerṣoni. Awọn enia si yọ̀, nitori nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ nitori pẹlu ọkàn pipe ni nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun Oluwa: pẹlupẹlu Dafidi ọba si yọ̀ gidigidi.
I. Kro 29:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi ọba sọ fún àpéjọpọ̀ àwọn eniyan pé, “Solomoni ọmọ mi, ẹnìkan ṣoṣo tí Ọlọrun yàn, ó kéré, kò tíì ní ìrírí, iṣẹ́ náà sì tóbi pupọ, nítorí ààfin náà kò ní wà fún eniyan, bíkòṣe fún OLUWA Ọlọrun. Mo ti sa ipá tèmi láti pèsè oríṣìíríṣìí nǹkan sílẹ̀ fún ilé OLUWA: wúrà fún àwọn ohun tí a nílò wúrà fún, fadaka fún àwọn ohun tí a nílò fadaka fún, idẹ fún àwọn ohun tí a nílò idẹ fún, irin fún àwọn ohun tí a nílò irin fún, pákó fún àwọn ohun tí a nílò pákó fún, lẹ́yìn náà, òkúta ìkọ́lé, òkúta olówó iyebíye, àwọn òkúta tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, ati mabu. Lẹ́yìn náà, yàtọ̀ fún gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti pèsè fún Tẹmpili Ọlọrun mi, mo ní ilé ìṣúra ti èmi alára, tí ó kún fún wúrà ati fadaka, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ mi sí ilé Ọlọrun mi, mo fi wọ́n sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé náà. Mo ti pèsè ẹgbẹẹdogun (3,000) ìwọ̀n talẹnti wúrà dáradára láti ilẹ̀ Ofiri, ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka tí a ti yọ́, láti fi bo gbogbo ògiri tẹmpili náà, ati àwọn ohun èlò mìíràn tí àwọn oníṣẹ́ ọnà yóo lò: wúrà fún àwọn ohun èlò wúrà, ati fadaka fún àwọn ohun èlò fadaka. Nisinsinyii, ninu yín, ta ló fẹ́ fi tinútinú ṣe ìtọrẹ, tí yóo sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí fún OLUWA?” Nígbà náà ni àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn alabojuto ohun ìní ọba, bẹ̀rẹ̀ sí dá ọrẹ àtinúwá jọ. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé OLUWA nìwọ̀nyí: ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) talẹnti wúrà, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaasan-an (18,000) ìwọ̀n talẹnti idẹ ati ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ìwọ̀n talẹnti irin. Gbogbo àwọn tí wọ́n ní òkúta olówó iyebíye ni wọ́n mú wọn wá tí wọ́n fi wọ́n sí ibi ìṣúra ilé OLUWA, tí ó wà lábẹ́ àbojútó Jehieli ará Geriṣoni. Inú àwọn eniyan náà dùn pé wọ́n fi tinútinú mú ọrẹ wá nítorí pé tọkàntọkàn ati tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi mú ọrẹ wá fún OLUWA; inú Dafidi ọba náà sì dùn pupọ pẹlu.
I. Kro 29:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà, ọba Dafidi sọ fún gbogbo àpéjọ pé: “Ọmọ mi Solomoni, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, sì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún OLúWA Ọlọ́run. Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti OLúWA yìí: Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ǹtì wúrà, ti wúrà ofiri àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà. Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún oríṣìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Nísinsin yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí OLúWA?” Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjì-dínlógún tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì irin. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí OLúWA. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.