I. Kro 15:1-4
I. Kro 15:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u. Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai. Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u. Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ.
I. Kro 15:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi kọ́ ọpọlọpọ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó tọ́jú ibìkan fún Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ó sì pa àgọ́ lé e lórí. Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.” Nítorí náà, Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sí Jerusalẹmu, kí wọ́n baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wá sí ibi tí ó pèsè sílẹ̀ fún un. Dafidi kó àwọn ọmọ Aaroni ati àwọn ọmọ Lefi jọ
I. Kro 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un. Nígbà náà Dafidi wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí OLúWA yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé. Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀