Sekariah 14:3-4

Sekariah 14:3-4 YCB

Nígbà náà ni OLúWA yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, Àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù.