Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.” Kì í sì í ṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró
Kà Romu 9
Feti si Romu 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Romu 9:6-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò