Romu 6:1-5

Romu 6:1-5 BMYO

Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jókòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i? Kí a má ri! Àwa ẹni tí ó ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa ó ha ṣe wà láààyè nínú rẹ̀ mọ́? Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun. Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde.