Romu 2:6-11

Romu 2:6-11 YCB

Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú: Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.