Saamu 128:1-6

Saamu 128:1-6 YCB

Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù OLúWA: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká. Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà, tí ó bẹ̀rù OLúWA. Kí OLúWA kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ. Láti àlàáfíà lára Israẹli.