Òwe Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Òwe
A kọ ìwé òwe láti mú àwọn ohun tí ó rúni lójú di fífihàn àti láti ní ìmọ̀ àti àlàyé fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, àti láti mú kí àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin ní ọgbọ́n sí i. Ní ti títẹnumọ́ “Ọmọ mi,” nínú ìwé yìí èyí tí ó wà nínú àwọn orí wọ̀nyí (1.0,8,10; 2.1; 3.1; 4.1; 5.1) ó tẹpẹlẹ mọ́ ọn nítorí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin láti mú wọn ní ayọ̀ àti ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Bákan náà ó tún sọ fún wa pé kí a ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, kí a má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara wa.
Ìwé yìí kọ ìhà búburú sí àwọn oníjà obìnrin àti àwọn tí kò le è pa ọ̀nà wọn mọ́. Ó fi yé wa wí pé ìdílé gbọdọ̀ jẹ́ ibi ìfẹ́, kì í ṣe ibi tí rúdurùdu ń gbé, èyí ló fi sọ pé “Òkèlè gbígbẹ, pẹ̀lú àlàáfíà, ó sàn ju ilé tí ó kún fún ẹran pípa pẹ̀lú ìjà” (17.1). Ó gbìyànjú láti tún sọ nípa fífi gbogbo agbára ṣiṣẹ́ àti kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣe ọ̀lẹ.
Àwọn ohun tó jẹ́ àmúṣọgbọ́n jù nínú ìwé yìí ni ó wà nínú orí mẹ́sàn-án àkọ́kọ́, níbi tó ti fi ọ̀nà àwọn ọlọ́gbọ́n wé ọ̀nà àwọn aṣiwèrè ènìyàn, ó ṣàlàyé pé àwọn mìíràn fi ayé wọn fún ọgbọ́n àwọn mìíràn fún òmùgọ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó rọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin láti gbé ìgbé ayé wọn ní ọ̀nà tí ó gbé ògo Ọlọ́run ga nítorí pé kí ọjọ́ alẹ́ wọn lè dára.
Kókó-ọ̀rọ̀
Ète àti pàtàkì 1.1-7.
Àwọn agbára tí ó wà nínú ọgbọ́n 1.8–9.18.
Pàtàkì gbígba òwe Solomoni 10.1–22.16.
Gbígba ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn 22.17–24.22.
Àfikún ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n 24.23-34.
Hesekiah gba àwọn òwe Solomoni 25.1–29.27.
Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri 30.1-33.
Àwọn ọ̀rọ̀ ọba Lemueli 31.1-9.
Obìnrin oníwà rere 31.10-31.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Òwe Ìfáàrà: BMYO

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀