Òwe 12:1-8

Òwe 12:1-8 YCB

Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n. Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ OLúWA ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi. A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu. Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà. Èrò àwọn olódodo tọ́, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn. Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn Olódodo gbà wọ́n là. A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin. A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.