Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú. Mo ni ìrètí nínú Jesu Olúwa, láti rán Timotiu sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúròó yín. Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín. Nítorí gbogbo wọn ni ó tọ́jú nǹkan ti ara wọn, kì í ṣe àwọn nǹkan ti Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé Timotiu pegedé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀, nínú iṣẹ́ ìhìnrere. Nítorí náà, mo ní ìrètí láti rán sí yín ní àìpẹ́ tí mo bá wòye bí yóò ti rí fún mi.
Kà Filipi 2
Feti si Filipi 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filipi 2:17-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò