Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí.
Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀, nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi, Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú. Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.
Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.